Ruga Settlement: Kí ló ń mú ìkùnsínú wá ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ko fẹ si ibi ti eeyan yoo kọju si lorileede Naijiria, ti ko ti ni ma gbọ ọrọ nipa Ruga settlement.
Ọrọ naa bi awọn ọrọ miran to nii ṣe pẹlu igbe aye awọn eeyan orile-ede yii, ti n mu ariwisi ọtọọtọ wa lati igba ati ijọba ti kede pe awọn fẹ ya aaye sọtọ fun un.
Bi awọn eeyan kan ṣe n tapa si agbekalẹ aagọ Fulani taa mọ si Ruga Settlement naa, lawọn miran n kan sara si ijọba lori igbesẹ naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Bo tilẹ jẹ pe ileesẹ BBC Yoruba ko gbe lẹyin ẹnikẹni, a lero pe o yẹ ki a ṣe alaye lori ohun ti Ruga tumọ si ati bi awọn eeyan ti ṣe n tumọ rẹ.
Ruga ati Fulani,nibo ni wọn ti papọ?
Ẹya Fulani lo pọ ninu awọn darandaran lorile-ede Naijiria.
Ọrọ Ruga ti ijọba si fi sọri aagọ to fẹ da silẹ fawọn darandaran yii, jẹ ọrọ kan ninu ede Fulani, eyi to tumọ si aaye tabi ibudo fawọn darandaran.

Oríṣun àwòrán, @ovieali
Gẹgẹ bi ohun ti akọroyin BBC, to se iwadi iroyin yii ti ṣe salaye, awọn darandaran maa n tẹdo si ibi ti wọn ba ti ri omi ati ounjẹ fawọn nnkan ọsin wọn.
Lọpọ igba, wọn ni wọn a maa kọ ile alamọ sibẹ, ti ijọba a si maa mu awọn ohun amayederun miran ba wọn nibẹ, bii ile iwe ati ile iwosan.
Ruga ko tumọ si ki eeyan jẹ gaba lori ẹlomiran. Itumọ yii si ni ọpọ fi n wo ohun ti Ruga tumọ si.
Ki nijọba n gbero pẹlu Ruga ti wọn fẹ da silẹ:
Aawọ laarin darandaran ati agbẹ ni ijọba lawọn fẹ dẹkun pẹlu idasilẹ aagọ fawọn to n da ẹran.
Ni Naijiria, awọn darandaran ati agbẹ a maa saaba kọlu ara wọn, ti eyi a si ma mu ọpọ ẹmi lọ.

Oríṣun àwòrán, @ovieali
Femi Adeshina, to jẹ oludamọran agba fun aarẹ feto iroyin nigba to n ṣalaye fun BBC sọ pe, ọna ati dẹkun wahala laarin agbẹ ati darandaran lawọn ṣe gbe igbimọ kalẹ lori ọrọ yii.
O ni awọn Gomina fọwọ si idasilẹ aagọ ifẹranjẹ lawọn ipinlẹ (Ranching) ṣugbọn nigba ti ikede Ruga jade ọpọ awọn Gomina tapa si.
Idi ti awọn kan ninu wọn fi siwaju ni pe Ruga fẹ gba ilẹ awọn eeyan wọn ni.
Ilẹ gbigba,Orukọ ti wọn sọ ati ọrọ Aje lo wa nidi aawọ naa
Loju opo Twitter ati lawọn aaye miran, awọn eeyan n tapa si Ruga nitori awọn idi lorisirisi.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1

End of X post, 2

End of X post, 3

End of X post, 4
Amọ ṣa, lẹyin ti a ṣe agbeyẹwo ohun ti wọn n sọ, a rii pe awọn idi ti a ka silẹ wọn yii lo n mu ikunsinu wa:
- Ki lo de ti wọn ṣe pee ni Ruga ti ko jẹ orukọ miran?
- Ai ni igbagbọ ninu ijọba
- Ṣe kii ṣe ọna lati gba ilẹ fawọn Fulani ni ijọba n wa pẹlu Ruga?
- Ki lo de ti ijọba fẹ na owo apapọ Naijiria sori iran kan?
- Ki lo de ti ijọba ko ṣe ran awọn elomiran lọwọ pẹlu iṣẹ ọwọ wọn, tabi okowo ti a mọ wọn mọ́ bi wọn ti ṣe fẹ ṣe fun awọn Fulani
Awọn nkan ti a ka silẹ wọnyii wa lara awọn nnkan ti o n jẹ ki ọrọ Ruga yii ma fa awuyewuye.
Nkan daadaa ti ijọba ni Ruga yoo mu wa:
Garba Sheu to jẹ agbẹnusọ fun ijọba salaye fun awọn akọroyin pe, Ruga jẹ ọna kan lati mu idagbasoke ba agbegbe ti wọn ba daa silẹ si.
O ni ijọba yoo pese gbogbo awọn ohun eelo amayedẹrun ti yoo jẹ ki sinsin ati tita ẹran gbooro si.
Ninu alaye rẹ to ṣe, Garba ni awọn oludokowo lati ile ati lẹyin odi, yoo laanfaani lati ṣowo ẹran ati awọn nnkan miran to maa n ti ati ara rẹ jade bi awọ.
Gbogbo ohun to ka silẹ yii dara ṣugbọn aini igbagbọ ninu ijọba lo jẹ pato idi to dakun wahala to wa nilẹ yii, to fi jẹ ki awọn eeyan mase ri dada kankan ninu igbesẹ yii.
Ṣe Ruga le dẹkun wahala laarin agbẹ ati darandaran?
Ibeere yii ni ibeere to jẹ awọn onwoye logun lẹnu igba ti awuyewuye Ruga yii ti bẹrẹ.

Oríṣun àwòrán, @Mr Saleem
Ninu nnkan ti pupọ ninu wọn sọ, wọn ni aawọ darandaran ati agbẹ kọja ọrọ mo fẹ dako, iwọ fẹ daran, bi kii ṣe pe ẹlẹyamẹya ti wọ.
Wọn ni, ni awọn ipinlẹ ti wahala yii ti peleke, dida Ruga silẹ lee dẹkun rẹ ṣugbọn ko si ẹni to lee fi ọwọ sọya pe ko ni da wahala silẹ.
Wọn ni ijọba ni lati jẹ ki awọn ara ilu ri wi pe ko si erongba kankan to yatọ si mimu idagbasoke ba awọn eeyan pẹlu igbesẹ dida Ruga settlement silẹ.