Bayelsa Attack: Ọ̀gá ọlápàá fọnmú pé kí wọn ṣàwárí àwọn ọ̀daràn tó pa ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, @newsbookng
Gọngọ sọ ni aarọ oni nigba ti awọn gende agbebọn kan ya bo agọ ọlọpa to wa ladugbo Ekpetiama to wa ni ilu Yenegoa, tii se olu ilu Bayelsa, ti wọn si gba ẹmi ọga ọlọpa DPO to wa nibẹ, Ọla Rosanla ati awọn ọlọpa mẹta miran, tawọn meji mii si farapa.
Nigba to n sọrọ lori isẹlẹ naa, ọga agba ọlọpa ilẹ wa, M.A Adamu kede pe ileesẹ ọlọpa ti n finmu finlẹ lori isẹlẹ naa lati se awari awọn ọbayejẹ ẹda to sisẹ laabi naa, ti wọn yoo si fi imu wọn ko ata ofin.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Bakan naa ni ọga agba ọlọpa pasẹ kia mọsa fawọn ọlọpa ọtẹlẹmuyẹ, atawọn akọsẹmọsẹ oluwadi iwa ọdaran pe lẹyẹosọka pe ki wọn sugba ileesẹ ọlọpa to wa ni ilu Yenegoa lati mu ki iwadi wọn ya kankan, ki akara awọn olubi ẹda naa lee su sepo kiakia.

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG
Adamu wa kẹdun pẹlu awọn mọlẹbi awọn agbofinro to jalaisi lọsan gangan ọhun, to si bu ọwọ nla fun wọn.
O tun rọ awọn olugbe adugbo Ekpetiama atawọn eeyan ipinlẹ Bayelsa lapapọ lati se suuru, ki wọn si fun awọn ọlọpa ni iroyin to ba yẹ, eyi ti yoo se iranwọ fun awọn ọlọpaa ninu iwadi wọn lati tete sawari awọn ọdaran naa.









