Benue Fire: Ọkọ̀ akérò 18 àtàwọn tó ń gbọ́n epo ló forí ṣọta ìjàmbá iná

Oríṣun àwòrán, @crimefightersng
Bi eeyan ba jẹ ori ahun, yoo bu sẹkun lọjọ Aje nigba ti tanka epo kan gbina, ti ẹmi toto ogoji si baa rin, tawọn eeyan miran ti wọn to ọgọta si farapa.
Awọn eeyan ti isẹlẹ naa soju wọn sọ fun BBC pe ọkọ epo to gbina naa, lo gbokiti lasiko to n gbinyanju lati pẹ koto kan silẹ loju popo to wọ ilu Markudi, tii se olu ilu ipinlẹ Benue.
Sugbọn gẹgẹ bii ise awọn eeyan to n wa ifa, lainaani ikilọ tawọn ọlọpa to wa nibi isẹlẹ naa n se fun wọn, wọn ti ọwọ ifa bọnu, pẹlu bi wọn se n gbọn epo pẹtiroolu to da silẹ latinu tanka naa, amọ ofo nla lo wọle tọ wọn nigba ti ọkọ epo naa sadede gba ina, eyi to mu ẹmi ọpọ wọn lọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Koda, ọrọ naa kanlẹ, o kan baale, to si tun kan jẹjẹ ni mo joko mi, nitori ọkọ bọọsi agbero kan to ko ero mejidinlogun, to fi aake kọri pe oun yoo tiraka gba ibi ti epo naa ti n da silẹ kọja, ni ina mu mọlẹ, to si pa gbogbo ero to wa ninu rẹ.
Ọkan lara awọn tisẹlẹ naa soju wọn, to ba BBC sọrọ ni "Nkan kan lo mu ki ọkọ epo naa bu gbamu fun ina, to si pa gbogbo ero to wa ninu ọkọ bọọsi kan atawọn eeyan to n gbọ epo, koda awọn ile ati sọọbu to wa nitori ibiti isẹlẹ naa ti waye, lo jona raurau.
A tun gbọ pe awọn osisẹ panapana meji lo farapa ninu ijamba ina naa, lasiko ti wọn n tiraka lati pa ina ọhun, ti wọn si ti gbe wọn lọ sile iwosan.









