Osun elections: APC pè fún àdúrà lórí ìdájọ́ kóòtù àgbà tó ń bọ̀ lórí gómìnà l'Ọ́ṣun

Oríṣun àwòrán, @OSUN_APC
Ọjọ Ẹti ọsẹ yii ni ile ẹjọ to ga julọ lorilẹ-ede Naijiria yoo gbe idajọ kalẹ lori ẹni gan an ni pato ti awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun dibo yan an gẹgẹ bii gomina wọn.
Ni oṣu kẹsan an ọdun 2018 lawọn eeyan ipinlẹ Ọṣun dibo lati yan gomina to wu wọn.
Lati igba naa wa, awọn meji to lewaju ninu esi ibo ọhun- Gboyega Oyetọla ti ẹgbẹ oṣelu APC pẹlu Ademọla Adeleke ti ẹgbẹ oṣelu PDP-ti n wọle jade nile ẹjọ kaakiri pẹlu ẹsun emi ni mo bori-iwọ kọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Adeleke bori ni ipele akọkọ ni ile ẹjọ to gbọ awuyewuye idibo l'Ọṣun, Oyetọla lo rẹrin bọ ni ile ẹjọ kotẹmilọrun, ni bayii ọrọ ti wa di ti ile ẹjọ to ga julọ.
Eyi lo mu ki alaga ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Ọṣun, Gboyega Famodun o ke sawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa lati wọ inu adura lọ bayii ki nnkan lee ṣe ẹnuure bọ fun wọn lati ile ẹjọ naa.
Ninu atẹjade kan to fi sita, Ọmọọba Famodun ni 'adura ṣe pataki lati wawọ awọn igbesẹ awọn ẹni ibi lori lori idajọ naa.'











