NFF: Ilé ẹjọ́ ní k'ọ́lọ́pàá ó wọ́ Amaju Pinnick wá síwájú òun lórí ẹ̀sùn ìkówójẹ

Oríṣun àwòrán, @thenff
Amaju Pinnick ni lati foju ba ile ẹjọ lori ọrọ yii.
Ile ẹjọ giga apapọ kan nilu Abuja ti paṣẹ ki awọn agbofinro o fi panpẹ ofin gbe aarẹ ajọ ere bọọlu lorilẹede Naijiria, NFF, Amaju Pinnick atawọn oṣiṣẹ ajọ naa mẹrin miran wa siwaju oun.
Onidajọ Ijeoma Ojukwu paṣẹ naa lẹyin ti Pinnick atawọn mẹrin naa kunna lati farahan niwaju ileẹjọ lati koju ẹsun ṣiṣe owo ajọ NFF baṣubaṣu eleyii ti wọn fi kan wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Bi o tilẹ jẹ wi pe agbẹjọro fun Pinnick atawọn ẹmẹwaa rẹ ṣalaye fun ile ẹjọ naa pe aiwa si ile ẹjọ wọn ko ṣẹyin bi wọn ṣe wa lara awọn ikọ ti ijọba apapọ ran lọ si orilẹ-ede Egypt fun idije ife ẹyẹ AFCON to n lọ lọwọ nibẹ.
Amọṣa, agbẹjọro fun ijọba ni irọ funfun balau ni awijare naa nitori oun fidi rẹ mulẹ pe orukọ Amaju Pinnick tabi eyikeyi ninu awọn mẹrin toku ko si lara awọn ikọ ti ijọba apapọ ran lọ.
Adajọ Ojukwu ni ko si ohun to kan Pinnick ati awọn mẹrin naa ni Egypt nitori awọn kọ ni agbabọọlu ti yoo pa itu nibẹ awọn si kọ ni awọn oṣiṣẹ ikọ naa ti yoo kọ wọn ni are bọọlu gbigba.
Yatọ si aarẹ NFF, Amaju Pinnick, awọn mẹrin ti wọn tun n jẹjọ niwaju ile ẹjọ naa ni igbakeji aarẹ akọkọ Ṣeyi Akinwunmi, igbakeji aarẹ keji Shehu Dikko, Sanusi Mohammed to jẹ akọwe agba ajọ naa pẹlu Yusuff Fresh to jẹ ọkan lara awọn ọmọ igbimọ alakoso ajọ naa.
Ijọba apapọ n fi ẹsun kan wọn pe wọn ṣe owo to to miliọnu mẹjọ ati irinwo ẹgbẹrun dọla owo ilẹ Amẹrika to jẹ owo ajọ NFF baṣubaṣu.
















