Ruga Settlement: A kò fipá mú ẹnikẹ́ni láti dá Ruga, àgọ́ Fulani sílẹ̀ -Iléeṣẹ́ aàrẹ

Buhari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ko si tipatipa ninu ki ẹ fun Fulani ni ilẹ̀ ipagó ni ipinlẹ yin ni ọrọ ijọba

Ko si tipa ninu ki o fi ilẹ̀ rẹ fun awọn Fulani darandaran -Ile iṣẹ aarẹ

Ileeṣẹ aarẹ ṣalaye ohun ti Ruga, aagọ Fulani jẹ pe o wa fun kiko awọn darandaran jọ soju kan ni.

Ninu atẹjade ti wọn fi sita ni wọn ti ṣalaye pe ko wa fun awọn Fulani nikan bikoṣe fun gbogbo awọn ti wọn n ṣiṣẹ ẹran ọsin.

Atẹjade naa ni ọja, ile iwosan eeyan ati ti ẹranko, ile iwe ati ọna to dara pẹlu omi to mọ gaara maa wa ninu aagọ kọọkan.

Ijọba ni wọn n ṣeto lori igbesẹ yii lati wa ojutu si iṣoro ija laarin awọn darandaran ati awọn agbẹ to n gba ọpọlọpọ ẹmi ati dukia.

Àkọlé fídíò, Arakunrin Fulani ni aigbede ara eni ni orisun ija pelu agbe

Awọn gomina ipinlẹ kọọkan ti fi ye ijọba apapọ pe awọn ko ni ilẹ ti awọn fẹ fun Fulani darandaran kankan ni agbegbe awọn rara.

Àkọlé fídíò, 'Fulani Ilorin l'ọkọ mi'

Gomina Samuel Ortum ti ipinlẹ Benue bi apẹrẹ ti ni ero ijọba apapọ yii ni lati tabuku awọn eeyan ipinlẹ oun.

Ortum ni Benue jẹ ipinlẹ to kun fun agbẹ alarojẹ ati alada nla, fun idi eyi awọn darandaran n ba ere oko wọn jẹ ni.

Kete ti awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ijọba apapọ de si Benue pẹlu erọ katakata lati wa bẹrẹ iṣẹ kikọ Ruga agọ Fulani lo ti ke gbajare pe oun ko faramọ.

Àkọlé fídíò, Odumakin sọrọ lori Fulani darandaran

Ijọba apapọ Naijiria ti fi ikede sita pe ko si dandan ninu fifi ilẹ rẹ silẹ rara.

Ati pe ijọba ko gbero lati fi agidi gba ilẹ lọwọ ẹnikẹni ni Naijiria fun awọn Fulani.

Àkọlé fídíò, Iraq, Palestine wà nínú orílẹ̀-èdè mẹ́wàá tí ìwádìí BBC ti wáyé

Atẹjade ti ijọba fi sita bayii ti yanana ọrọ naa pé ipinlẹ mejila pere lo tii fi ifẹ han pe awọn faramọ igbesẹ ijọba naa.

Àkọlé fídíò, Ijinigbe: BBC ṣe ìwádìí bí ikọ̀ IRT ṣe ń gbéjà ko awọn ajinigbe lójú

Ijọba ni iṣẹ yoo bẹrẹ ni awọn ipinlẹ ti wọn ti faramọ kikọ aàgọ́ Fulani ni ipinlẹ wọn.

Àkọlé fídíò, Afcon 2019: Àwọn olólùfẹ́ Super Eagles fẹ́ kí Rohr tún wọn tò

Atẹjade naa ni tootọ ni ijọba ti ya awọn ile kan sọtọ ni gbogbo ipinlẹ Naijiria lati fi kọ aagọ Fulani ṣugbọn ko si tipatipa ninu ki ẹnikẹni fi ilẹ rẹ silẹ.

Àkọlé fídíò, International Day Against Drug Abuse and Trafficking: ìdí ti mo fi ń mu oògùn olóró