OSCOTECH: Òṣìṣẹ́ mẹ́rin ilé ìwé gíga l'Oṣun gb'òmìnira lọ́wọ́ ajínigbé darandaran Fulani

Oríṣun àwòrán, oscotechesaoke
Awọn oṣiṣẹ mẹrin ile iwe gbogbo nṣe OSCOTECH, Esa Oke nipinlẹ Oṣun ti gba ominira lọwọ awọn ajinigbe Fulani darandaran.
Agbẹnusọ fun ile iṣẹ ọlọpaa ni Ipinlẹ Oṣun SP Folasade Odoro fidi ọrọ naa mulẹ laarọ ọjọ Ẹti.
O ṣalaye pe owurọ ọjọ Ẹti ni wọn gba ominira wọn ti wọn si ti darapọ mọ awọn ẹbi wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Agbẹnusọ fun ile iṣẹ ọlọpaa kọ lati sọ bo ya awọn ajinigbe ọun gba owo ki wọn to fi wọn silẹ.
Ṣugbọn o fi kun ọrọ rẹ pe ile iṣẹ ọlọpaa yoo ri daju pe ọwọ ofin ba awọn ajinigbe ọun.
Lọjó Iṣẹgun ni awọn agbebọn darandaran ji awọn oṣiṣẹ mẹjọ ile iwe naa gbe, ṣugbọn wọn da mẹrin ninu wọn silẹ L'Ọjọru.
Wọn pa ẹnikan ninu awọn oṣiṣẹ ọun ti o gbiyanju lati sa lọ nigba ti awọn ajinigbe naa de.









