2019 Elections: Saraki, Dino ní kí Yorùbá dìbò ààrẹ fún Atiku
Aare igbimọ aṣofin agba l'Abuja, Bukọla Saraki kesi gbogbo ọmọ Yoruba lati gbaruku ti Atiku Abubakar ninu idibo aarẹ ọdun 2019 nitori awọ rẹ nikan lo ka oju inu iṣakoso orilẹede Naijiria.
O fi idaniloju han wi le ijọba Atiku yoo tu tolori-tẹlẹmu lara nitori saaju asiko lo ti n lese iṣẹ lọpọ yanturu fun ọpọlọpọ awọn ọdọ ti ko riṣẹ ṣe nipasẹ awọn ile iṣẹ aladani ti o ṣe agbekalẹ rẹ.

Ninu ọrọ tiẹ, Gomina ipinlẹ Ogun tẹlẹri, Ọtunba Gbenga daniel ti o tun jẹ aṣoju ipolongo ibo fun ẹgbẹ oṣelu PDP, Ọtunba Gbenga Daniel ti ṣe alaye wipe ibo alajọbi ni ibo ti awọn ọmọ bibi ilẹ Yoruba yoo di fun Atiku Abubakar ninu eto idibo si ipo aarẹ lọdun 2019.
Gomina tẹlẹri ọhun sọ ọrọ naa di mimọ nibi akanṣe eto ipolongo ibo fun oludije si ipo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ti o waye l'Ọjọbọ ni gbagede Mapo nilu Ibadan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Awọn aworan oriṣiriṣi nibi ipolongo Atiku n'Ibadan





Ọgọrọ awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu PDP lo pejupesẹ sibi ipolongo naa. Lati awọn ipinlẹ to n bẹ lẹkun Iwọ Oorun ni awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ti kora jọpọ fun akanṣe eto naa.

lara awọn eeyan pataki ti wọn n reti nibẹ ni awọn alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, igbimọ alakoso, awọn oludije ninu ẹgbẹ oṣelu naa ati Atiku Abubakar to jẹ ọmọ oye fun ẹgbẹ oṣelu PDP ninu idije si ipo aarẹ lọdun 2019.

Lati aago mejila lo ti yẹ ki eto naa bẹrẹ, ṣugbọn awọn alẹnulọrọ ti wọn n reti ko tii de si ibi eto naa.

Lara awọn oṣere to darapọ mọ ipolongo naa ni Sanyẹri Afọnja, Murphy Afọlabi, Kunle Afod, Kamilu Kampo, Saheed Oṣupa ati Taiye Currency.














