Lere Olayinka: Fayoṣe ti ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn

Fayose pẹlu POP lọrun
Àkọlé àwòrán, Fayose kàgbákò ìjàmbá ọkọ̀
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti tẹ́lẹ̀ rí, Ayọdele Fayoṣe ní ìjàmbá ọkọ̀ lọ́jọ́rú ọ̀sẹ̀ lórí afárá Third Mainland ní ìpínlẹ̀ Eko.

Olùrànlọ́wọ́ gómìnà àná yìí, Lere Ọlayinka ló fi síta lójú òpó Twitter rẹ̀ pé Ayodele Fayoṣe ní ìjàmbá ọkọ̀.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ẹ̀wẹ̀, ó ni ipò tí Fayoṣe wà kò burú ṣùgbọ́n ó ti wà nílé ìwòsàn báyìí tó ń gba ìtọ́jú.

Àkọlé fídíò, Ìbejì Oníbẹ̀mbẹ́ Òru: Owó, ọmọ àbí aya kò leè yà wá