Electoral bill 2018: Èrèèdí wàhálà láàárín Buhari àtàwọn aṣòfin àpapọ̀ lórí òfin ìdìbò 2018

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni ọjọ Ẹti, ọjọ keje oṣu kejila ọdun 2018 ni gbedeke ti ofin la silẹ fun ẹmi abadofin fun igbọwọle aarẹ yoo wa sopin.
Eyi tumọ si pe bi aarẹ Buhari ko ba buwọlu abadofin naa ki ọjọ ẹti to lọ, abadofin naa fori ṣanpọn niyii.
Pẹlu bi orilẹede Naijiria ṣe n gbaradi fun idibo apapọ ni ọdun 2019, ọpọ onwoye lo ti n woo bi eyi yoo ṣe ri pẹlu ilana ati igbaradi fun idibo naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ninu iwe atẹjade kan eyi ti o fi sita, aarẹ ile aṣofin apapọ orilẹede Naijiria, Sẹnetọ Bukọla Saraki ni kii ṣe araalu atawọn onwoye nikan ni ọrọ naa n kọ lominu, o ni awọn aṣofin pẹlu ti n ranṣẹ si oun lati mọ idi ti aarẹ fi n wọsẹ nilẹ lori bibuwọlu abadofin naa. O ni bi aarẹ ko ba buwọlu abadofin yii, ko si bi awọn aṣofin ko ṣe ni gbe igbesẹ naa.

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad
Ninu ọrọ ti wọn ba BBC News Yoruba sọ awọn aṣofin ajafẹtọ araalu meji kan, Malachi Ugumadu ati Iniebe Effiong pẹlu kọminu lori rẹ, ṣugbọn wọn ni iwe ofin orilẹede Naijiria ti ọdun 1999 ti la ọna kalẹ fun abayọ.
Ọna abayọ ọhun, gẹgẹ bi wọn ṣe sọ ni pe awọn aṣofin lee pa aṣẹ waa lori abadofin naa ti yoo si di ofin.
Aṣofin Malachi Ugumadu ti o jẹ alaga ajọ ti o n ja fun ẹtọ araalu, CDHR lorilẹede Naijiria ṣalaye pe irufẹ iṣẹlẹ bayii ti waye ri ni ọdun 2006 ṣugbọn ti awọn aṣofin apapọ lo agbara aṣẹ waa lati buwọlu iwe abadofin naa funra wọn.
Kini ipa ti o lee ni lori idibo ọdun 2019?

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad
Amofin Effiong ni aifi ọwọ si iwe ofin eto idibo yii yoo mu ọpọlọpọ ibeere jade lori iduro ṣinṣin eto idibo naa nitori iwe ofin ti o yẹ ko mu ọpọlọpọ atunto ba eto naa ni eyi.
Gẹgẹ bi o ṣe sọ awọn ilana tuntun bii lilo ẹrọ idibo ti o wa ninu abadofin yii jẹ itẹsiwaju fun eto idibo ti ko ni ẹja-n-bakan ninu lorilẹede Naijiria, nitori naa ko si idi fun aarẹ lati ma buwọlu u.
Amofin Malachi Ugumadu ni bi aarẹ ba kuna lati ṣe ohun ti o tọ, ki awọn asofin tẹ siwaju lati fi aṣẹ waa wọn gbe ofin naa wọle.
Ki lo n faa gbọnmi sii omi ko to lori abadofin naa laaarin ẹka aṣofin ati iṣakoso?

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad
Eyi kọ ni igba akọkọ ti edeaiyede yoo maa waye lori abadofin yii. Koda eyi to kẹyin ni aarẹ ti beere fun atunṣe awọn abala kan ninu ofin naa eleyi ti awọn aṣofin ti ṣe atunṣe si ki wọn to tun daa pada.
Ninu ọrọ rẹ, amofin Malachi Ugumadu ni lara awọn ohun ti o n fa gbonmisii laarin ẹka ijọba mejeeji ni ọrọ lilo ẹrọ idibo fun idibo labẹ ofin.
O ni ṣaaju asiko yii ko si ẹni to lee lo akude lori ẹrọ idibo yii lati fi gbe ẹjọ kalẹ niwaju ile ẹjọ, eleyii ti o ni abadofin yii mu atunṣe ba.
Ohun keji ti o wa ninu abadofin yii eyi ti awọn aṣofin fi kun un ni fifun ajọ INEC ni agbara labẹ ofin lati lee gbe igbesẹ to tọ lori awọn idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu yoowu ti wọn ba ri pe ko lọ ni ilana ti ofinla kalẹ.
"Tẹlẹtẹlẹ, bi INEC ba lọ si awọn ipade abẹle awọn ẹgbẹ oṣelu kaakiri, oluworan ni wsn maa n ṣe nibẹ, wọn ko lẹtọ lati gbe igbesẹ lori iwa aitọ yoowu ti wọn ba kẹẹfin nibẹ"
Ni tirẹ, amofin Effiong ni 'Ko si awawi kan fun aarẹ lati maṣe buwọlu abadofin yii. Ayafi ti o ba jẹ pe aarẹ kan nlo iwa iṣegbe fun ẹgbẹ oṣelu abi oun ti yoo boo lẹsẹ nikan ni o ku."













