Electoral bill 2018: Buhari àtàwọn aṣòfin àpapọ̀ leè gbéná wojú ara wọn láìpẹ́

Oríṣun àwòrán, Bukola Saraki
Afaimọ ki ẹka aṣofin ati ẹka iiṣakoso o maa gbe ina woju ara wọn ni awọn ọjọ ti o n ṣaaju idibo apapọ bayii o.
Ko si idi meji ti eyi lee fi waye ju lori ọrọ bi aarẹ ṣe n fi ẹsẹ falẹ lori ọrọ bibu ọwọ lu abadofin tuntun lori ọrọ ilana idibo lorilẹede Naijiria.
Aarẹ ile aṣofin agba lorilẹede Naijiria, Sẹnetọ Bukọla Saraki lo tun mu ọrọ naa wa si iranti ninu atẹjade kan to fi sita pe ki aarẹ Buhari o kọ eti ikun si ọrs awọn kan ti wọn n ke sii pe ko maa buwọlu abadofin naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Saraki ni ohun ti o tọna ni ki aarẹ pa ọrọ oṣelu ti ki o si gbe igbesẹ lori ohun to pe ni 'anfani orilẹede Naijiria' ki o si buwọlu ofin naa.
Ọrọ nipa bibuwọlu ofin ilana idibo tuntun yii ti wa nilẹ fun ọjọ pipọ. Akọkọ rẹ ti ile aṣofin fi ṣọwọ si aarẹ ko gba igbọwọle aarẹ nitopri ohun ti aarẹ pe ni aidọgba awọn abala kan ninu abadofin naa.
Awọn aṣofin apapọ ṣe atunṣe si abadofin naa lẹyin ti aarẹ daa pada fun wọn ki ọrọ to de ipele ti o wa bayii.
Saraki ni awọn aṣofin gbogbo ni wọn ti n da oun laamu lati fi aidunu wọn han lori bi aarẹ ṣe n fi ẹsẹ falẹ lori rẹ paapaajulọ bi oṣu kan ti ofin la kalẹ fun abadoofin naa ti ṣe fẹ pari ni ọjọ diẹ si asiko yii.
Saraki woye pe "bi ọrọ ṣe bẹrẹ niyi lasiko ti awọn ẹgbẹ kan bii ABN ko ara js lọ si ile ẹjọ lati dena kikede esi idibo June 12, ọgbọn yii kan naa lawọn ẹgbẹ ati eeyan kan tun fẹ maa lo bayii lati dena bibuwọlu ofin ilana idibo tuntun yii."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post













