Èmi kò mọ obìrin tí DSS mú rí —Aisha Buhari

Aisha Buhari

Oríṣun àwòrán, Twitter/@AishaBuhari

Ìyàwó ààrẹ Nàìjíríà, Aisha Buhari ti sọ wí pé òun kò mọ ọbìrin tí ilé iṣẹ́ ọ̀telẹ̀múyé orílẹ̀èdè Nàìjíríà, DSS, fi ẹ̀sùn jìbìti kan rí.

Àtẹ̀jáde kan tí agbenusọ ìyàwó ààre náà, Suleiman Haruna, fi síta sọ pé arábìrin Aisha Muhammadu Buhari ń bá àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó rọ̀ mọ́ ìwádìí tí ilé iṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ (DSS) ń ṣe nípa ìwà jìbìtì kan.

Aisha Buhari sọ wí pé òun kò ní ǹkankan ṣe pẹ̀lú ìwà jìbìtì tí ilé iṣẹ́ DSS ń ṣe ìwádí rẹ̀ lọ́wọ́.

Lọ́jọ́rú ni ilé iṣẹ́ DSS ṣe àfihàn obìnrin kan tí wọ́n fi ẹ̀sùn lílo ilé ààrẹ láti lu àwọn èèyàn ní jìbìtì.

Ṣùgbọ́n nínú àtẹ̀jáde tó fi síta lọ́jọ́bọ, Asiha Buhari sọ pé obìnrin tó ń jẹ́ Mariyatu tí wọ́n sì ń pè ní Amina Mohammed kìí ṣe ọmọ ìya òun.

Ìyàwó ààrẹ Nàìjíríà náà sọ pé gbogbo òṣìṣẹ́ tí wọ́n bá ká àìṣe dédé mọ́ lọ́wọ́ yó fojú winá òfin.

Obìnrin "ayédèrú"

Oríṣun àwòrán, .

Àkọlé àwòrán, Obìnrin tí DSS fi ẹ̀sùn kan pé ó ń ọ̀nà alùmọkọ́rọ́yín wọ ilé ààrẹ l'Abuja láti lo gbájúẹ náà rèé

Ìròyìn sọ pé obìnrin yìí máà ń lo onírúurú ọ̀nà alùmọkọ́rọ́yín wọ ilé ààrẹ l'Abuja láti lo gbájúẹ pẹ̀lú àwọn ayédèrú òwò ṣíṣe ṣùgbọ́n ó ti kábamọ̀ ìwà rẹ̀ báyìí.

Ilé iṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ sọ pé Amina Muhammed tí kọ́kọ́ sọ pé oun ní aya gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi lójúnà àti rí ààyè wọ Aso Rock ní ìlú Abuja.

Ilé iṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ sọ pé Amina Muhammed tí kọ́kọ́ sọ pé oun ní aya gómìnà Kogi lójúnà àti rí ààyè wọ Aso Rock ní ìlú Abuja.

Lẹ́yìn èyí ló bẹ̀rẹ̀ sí ní ráńṣẹ́ sí àwọn ènìyàn lórúkọ ayá ààrẹ Muhammadu Buhari.

Níbi ìpàdé àwọn oníròyìn tí wọn ti sàlàyé ọ̀nà tí wọn gba mú arábìnrin Mohammed ṣe ló kígbe pé "irọ́ ní''