APC: A kò ní ìjìyà kankan fún Amosun lórí ìgbésẹ̀ rẹ̀

Ibikunle Amosun

Oríṣun àwòrán, @Govsia

Ẹgbẹ oṣelu APC ti fesi lori ikede kan ti Gomina ipinlẹ Ogun, Ibikunle Amosun se laipẹ yii pe, oun yoo gbe lẹyin oludije fẹgbẹ oselu APM, Adekunle Akinlade lati di gomina ipinlẹ Ogun lọdun 2019.

Ọjọ Aje ni Gomina Amosun fọwọ idaniloju sọya bẹẹ, to si tun se adura aseyọri fun oludije naa.

Ninu ọrọ ẹgbẹ, APC ni Gomina Ibikunle Amosun ko ti kọja aaye rẹ pẹlu bo ṣe ni oun ko ni gbè lẹyin oludije ẹgbẹ APC, fun ipo Gomina nipinlẹ Ogun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Ọdẹrinde Oníjaàálá: Ìjálá mi máa ń mú káwọn onísẹ́ ibi gbàgbé láti sebi

Akọwe ipolongo fẹgbẹ APC, Mallam Lanre Issa Onilu ni, Amosun lẹtọ labẹ ofin ẹgbẹ APC, lati ṣọ ero ọkan rẹ laisi idiwọ kankan.

Issa kede ọrọ yi ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ile iṣẹ BBC Yoruba.

"A ko le ni ki ọmọ ẹgbe ma sọ ero ọkan rẹ amọ to ba jẹ wi pe o sọ nnkan to ba tako ẹgbẹ nigba yẹn lẹgbẹ to le gbe igbesẹ lati fi iya to tọ jẹ''

Onilu ni boya igbonara lo mu ki Amosun ṣọ oun to ṣọ ati wi pe ko ti ṣọ ọrọ na di mimuṣẹ.

Ami idanimọ APC

Oríṣun àwòrán, @APCNigeria

Àkọlé àwòrán, Aáwọ̀ abẹ́nú lóríṣiiríṣìí ló ń ṣẹlẹ̀ ninu ẹgbẹ APC lorilẹ-ede Naijiria

O tẹsiwaju wi pe awọn ti ''gbe igbimọ ti yoo pẹtu saawọ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ kalẹ.O ṣi ṣeeṣe ki wọn yanju ohun ti o'n mu ki Gomina Amosun ṣọ wi pe oun ko ni gbe lẹyin oludije ẹgbẹ''

Bi a ko ba gbagbe,Gomina Ibikunle Amosun fi saaju fi àtẹ̀jáde kan síta nínú ìpàdé tó ṣe pẹ̀lú àwọn adarí ẹgbẹ́ káàkiri ìjọba ìbílẹ̀ pe oun yoo fi ẹgbẹ oselu APC silẹ.

Lẹyin wa igba naa ni o ri tikẹti gba lati du ipo asofin labẹ asia ẹgbẹ APC ṣugbọn ti aayo rẹ fun ipo Gomina Adekunle Akinlade ko ri tikẹti ẹgbẹ gba.

Eyi lo mu ki Gomina Amosun leri wi pe ohun yoo gbe lẹyin Adekunle Akinlade to ti gba tikẹti ẹgbẹ oselu miiran ti ṣe Alliied People's Movement, APM.

Akinlade ni yóò di gómìnà tuntun ní ìpínlẹ̀ Ogun- Amosun

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ogun Ibikunle Amosun sọ pé òun ti sàdúrà fún olùdíje Gomina nínú ẹgbẹ́ òṣèlú Alliied People's Movement APM ní ìpínlẹ̀ Ogun Adekunle Akinlade láti lépa ohun ti ọkan rẹ̀ ń fẹ́ nínú ẹgbẹ́ náà.

Amosun ni ohun kìí ṣe ẹni ti yóò máà farapamọ sábẹ́ ìka kan, Ó sàlayé lónìí ọjọ́ ajé níbi ìpadé àwọn ọmọ lẹ́yìn rẹ̀, tó wáyé nío ilé igbé ààrẹ tó wà ní Ibara Housing Estate Abeokuta.

Gómìnà tẹnu mọ́ọ pé ifarajì rẹ̀ láti ríi dájú pé Akinlade yóò górí àléfà lẹ́yìn ohun nínú oṣù kárún ọdún 2019 àti pé kò sí ọ̀nà abáyọ fún Dapọ Abiodun nítori pé ó jí nkan tó tọ́ sí Akinlade ninú ẹgbẹ́ APC ní.

Àwọn aṣòfin 26 fi ẹgbẹ́ òṣèlú APC 26 sílẹ̀ lọ sí APM

Ami idanimọ APC

Oríṣun àwòrán, APc

Àkọlé àwòrán, Èyí ni ara àwọn ìgbésẹ̀ tí ó ń ṣàfihàn èdèaìyedè nínú agbo ẹgbẹ́ òṣèlù APC ní ìpínlẹ̀ Ògùn.

Ó kéré tán ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n nínu ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) ló ti kúrò lọ sí ẹgbẹ́ òṣèlú Allied Peoples Movement APM

Jíjá ẹgbẹ́ òṣèlú APC sílẹ̀ yìí wáyé lẹ́yìn òṣẹ̀ kan tí eni àmì òróró Gominà Ibikunle Amosun fún ipò gómìnà ní ìpínlẹ̀ Ogun lọ sí inú ẹgbẹ́ APM.

Agbẹnusọ fún àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ asofin Lamidi Olatunji pé àwọnti fi ìmọ sọkan láti lọ mú èróngbà wọn ṣẹ ní nínú ẹgbk òṣèlú APM.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Olatunji added that: "We also wish to acknowledge the fatherly role of President Muhammadu Buhari in seeking to sustain the tenets of democracy, fairness and equity in the resolution of the crisis in Ogun APC.

Olatunji fí kún-un pé '' a ṣe àkíyèsí akitikyan àtí ipò bàbá ti ààrẹ Muhammadu Buhari láti ríi dájú pé ìṣèjọba awà-arawa tún gbilẹ̀ sí, àìfárí apákan dá apákan si àti ìwà aparò kàn o ga jú ìkan lọ ti ó fi kọ àwọn ọmọ ẹgbẹ́".

"Ó ṣe ni láànú pé gbogbo akitikyan ààrẹ ní àwọn kan yí dànù tí wọn sì kọ̀ jálẹ̀ láti gba ẹkùn ìwọ̀-òòrún- guusu pada sí àyé ìmunísìn ní bi tí àwọn àìkúkú joyè ó sàn ju ẹnu mi ò kálùú.

Kọmísọnà fún ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ Dayo Adeneyhe àti Modupe Mujota kọmisọnà fún ètò ẹkọ wà lárá àwọn tó kọ́wọ̀ọ̀ rí lọsí inú ẹgbẹ́ APM