Ọ̀ọ̀ni Ilé Ifẹ̀: Ọ̀rúnmìlà ni ó kọ́kọ́ lo 'Google' láàgbáyé

Ọọni ile Ife
Àkọlé àwòrán, Kabiyesi ni Yoruba gbọdọ ranti mọ ipo wọn gẹgẹ bii ẹya ti ko ṣee fi ọwọ rọ sẹyin ni agbaye

Ọọni ile ifẹ, Adeyẹye Ogunwusi ti ṣalaye pe ilẹ Yoruba ni ipa nla ti o ko lori idagbasoke imọ ẹrọ ati imọ sayẹnsi lagbaye.

Ọọni Ogunwusi ni Orunmila ni o kọkọ gbe imọ eroja iṣẹ lori ayelujara ti a mọ si 'Google' kalẹ lati ọpọ ọdun sẹyin ki o to di wi pe oyinbo gbee kalẹ.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ lasiko eto facebook live lori ikanni ayelujara facebook ni o sọrọ yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọọni Ifẹ ni ko si ẹsin kan ti o ju ẹsin kan lọ nitori ninu ifẹ ati iṣọkan ni gbogbo ẹsin ti waye.

O ni iṣẹ ti awọn alalẹ gbe le oun lọwọ ni lati lọ igi alaafia ni alọye laaarin awọn lọbalọba ati ọmọ bibi ilẹ Yoruba lagbaye.

O ni ko si ija tabi ikunsinu laarin awọn Ọbalaye ni ilẹ Yoruba mọ nitori alaafia ti jọba.

"Aifagba fun ẹnikan ni o n fa wahala laaarin awọn ọbalaye ilẹ Yoruba. Loootọ emi ni olori gbogbo Ọbalaye ni ilẹ Yoruba, sibẹ awọn agba ọba n bẹ ti mo ba lori itẹ ti mo si ni lati fi ọwọ fun gẹgẹ bi agba lori ilẹ. Ki Ọlọrun ki o bawa lọọra ẹmi wọn ki wọn tubọ pẹ fun wa."