Ladi Àdebutu ni olùdíje gómìnà wa l'Ogun —PDP

Àwòran Ladi Adebutu

Oríṣun àwòrán, Facebook/LadiAdebutu

Àkọlé àwòrán, Ladi Adebutu

Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ti ké gbàjarè pé Ladi Adebutu ni oludíje ipò gómìnà ní ìpílẹ̀ Ogun fún ẹgbẹ́ náà.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ẹgbẹ́ náà, Kola Ologbodiyan, fi léde sọ wí pé iyè-méjì nípa olùdíje gómìnà ẹgbẹ́ náà ní ìpìnlẹ̀ Ogun.

Ìkéde náà wáyé lásìkò tí àwọn ìròyìn kan sọ wí pé Sẹ́nétọ̀ Buruji Kashamu ni olùdíje fún ìpò náà nínú ẹgbẹ́ PDP.

Ologbodiyan sọ wí pé Ladi Adebutu ni ẹni tí wọn dìbò yàn níbi ìbò abẹ́lé tí wọ́n dì lábẹ́ ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe PDP .

Agbẹnusọ PDP náà bá kéde pé kí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ kọ̀yìn sí gbogbo ẹni tó bá ń dábàá pé òun ni yóò du ipò náà lábé àsìá PDP.

Àwòran ìpolongo Sínátọ̀ Buruji Kashamu àti dókítà Reuben Abati

Oríṣun àwòrán, Facebook

Àkọlé àwòrán, Ìkéde náà wáyé lásìkò tí àwọn ìròyìn kan sọ wí pé Sínátọ̀ Buruji Kashamu ni olùdíje fún ìpò náà nínú ẹgbẹ́ PDP

Sẹ́nétọ̀ Buruji Kashamu kò tíì sọ sí ọ̀rọ̀ náà lásìkò tí à ń ko ìròyìn yìí jọ.