ECOWAS: Orílẹ̀èdè 15 tó wà nínú àjọ ECOWAS yóò bẹ̀rẹ̀ sí níì ná owó kan nàá l'ọ́dún 2020

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn olori orilẹede to wa ninu ajọ Iwọ oorun Afrika, ṣe ipade nilu Abuja fun ipade karundinlọgọta lati dibo yan alaga tuntun, ti wọn si tun sọrọ lori bi ẹkùn naa yoo ṣe maa na owo kan naa.
Awọn orilẹede mẹẹdogun to wa ninu ajọ naa ti ni afojusun lati maa na owo kan naa nigba ti yoo ba fi di ọdun 2020.
Nitori afojusun yii, awọn minisita eto inawo ati awọn gomina banki apapọ lawọn orilẹede naa ṣepade laipẹ yii lati gbaradi fun ṣiṣe idasilẹ owo ti gbogbo awọn orilẹede naa yoo ma na, ati bi paṣipaarọ rẹ yoo ṣe ri.
Nibi ipade ti awọn aarẹ n ṣe yii, wọn yoo ṣe ayẹwo ibi ti awọn minisita naa ba iṣẹ de.
Lọwọlọwọ, Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ni alaga ajọ Ecowas.
Lara oun ti wọn yoo tun jiroro le lori nibi ipade naa ni wahala oṣelu to n waye ni Guinea Bissau.









