Elisha Abbo: Àwọn alátakò mi nínú òsèlú ló gbé fídíò mi síta

Asofin Elisha Abbo ti Adamawa

Oríṣun àwòrán, Elisha Abbo

Sẹnetọ kan to n soju ẹkun idibo ariwa Adamawa, Elisha Abbo ti di olokiki latari bi fidio kan ṣe ṣe afihan bo ṣe lu arabinrin abiyamọ kan bolẹ ninu ṣọọbu kan, ti wọn ti n ta awọn nkan ibalopọ, Banex Plaza ni Abuja.

Nigba ti BBC kan si ṣẹnetọ naa, o ni iṣẹlẹ naa ti waye lati ọjọ Kọkanla oṣu Kẹta ọdun 2019 bo tilẹ jẹ wipe awọn iroyin to n sọrọ nipa isẹlẹ naa ni ọjọ Kọkanla oṣu Karun un ọdun 2019 lo waye.

Abbo ni awọn to wa ninu ṣọọbu naa kọkọ lu aburo oun bolẹ, ti wọn si gba ẹjẹ lẹnu rẹ ni oun ṣe lu awọn naa bolẹ.

Àkọlé fídíò, 'Àjẹ́, eégún, kí ni wọn ò pè mí tán tórí Vitiligo lára mi'

Ṣugbọn ohun ti fidio naa ṣe afihan rẹ yatọ si ohun to sọ.

Ọrọ to sọ ninu fidio naa fihan wipe, ohun ti abiyamọ to lu naa sọ ni wipe, ko fi ara balẹ nigba to n pariwo, ni inu ba bi.

Abbo ni awọn ọta oun ninu oṣelu lo faa, ti fidio naa fi jade ni akoko yii lẹyin to ti pẹ ti iṣẹlẹ naa ti waye sẹyin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, A nilo agọ ọlọpa ni Orin Ekiti fún aabo wa -Falua

O tun ni oun ko lọ lati lọ ra nkan ibalopọ ninu ṣọọbu naa. O ni ṣokoto ati aṣọ ni oun fẹ lọ ra, ki aburo oun obinrin to tẹle oun to mu oun lọ inu ṣọọbu ti wọn ti n ta ohun ibalopọ.

Ajọ Amnesty International ti da si ọrọ naa, wọn ni ileeṣẹ ọlọpaa gbọdọ wadi Abbo ni kiakia. Wọn ṣalaye wipe, idajọ gbọdọ ṣẹlẹ lori ọrọ naa.

Àkọlé fídíò, Kayefi BBC Yorùba: Bàbá ọmọ, Mọ́ṣúárì, Ọlọ́pàá kẹ́jọ́ rò nípa òkú ọmọ tó pòórá