Ruga Settlement: Ààrẹ Muhammadu Buhari ti dá èròǹgbà láti dá àgọ́ daran-daran sílẹ̀ dúró

Darandaran

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ aarẹ Naijiria ti fidi rẹ mulẹ fun BBC pe Aarẹ Muhammadu Buhari ti da erongba lati ṣe idasilẹ Agọ daran-daran, RUGA, silẹ duro.

Bashir Ahmad to jẹ oluranlọwọ fun Aarẹ Buhari sọ pe lootọ ni ijọba ti da eto RUGA duro naa.

Eyi waye lẹyin ti Igbakeji Aarẹ, Yẹmi Ọṣinbajo ati awọn gomina ṣe ipade bonkẹlẹ ni ilu Abuja lati jiroro lori erongba ijọba apapọ.

Ṣaaju ni ileeṣẹ aarẹ ṣalaye pe awọn ọmọ orilẹede Naijiria yoo mọ boya ijọba apapọ yoo tẹsiwaju pẹlu eto naa ti o ti n da ọpọ awuyewuye silẹ, l'Ọjọru.

Ati wi pe awọn gomina ipinlẹ ni yoo sọ boya idasilẹ RUGA yoo waye.

Àkọlé fídíò, CAN: Samson ni ọrọ awọn ajinigbe ti gba àpérò ní Naijiria

Ni ọsan Ọjọru ni iroyin kan jade lati inu ọkan lara awọn iwe iroyin ori ayelujara lorilẹede Naijiria pe Aarẹ Muhammadu Buhari ti gba lati da eto naa duro.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Amọṣa, nigba ti BBC News Yoruba pe agbẹnusọ fun aarẹ, Garba Shehu lati mọ otitọ to wa ninu ọrọ naa, o ni oun gbogbo yoo han kedere sawọn ọmọ Naijiria lẹyin ipade ti igbakeji aarẹ, Yẹmi Oṣibajo n ṣe pẹlawọn gomina nilu Abuja.

"Ajọ awọn gomina lorilẹede Naijiria yoo kede igbesẹ to kan lori ọrọ RUGA" ni ọrọ Garba Shehu fi da ileeṣẹ wa lohun.