Senator Elisha Abbo: Ilé aṣòfin àgbà gbé ìgbìmọ̀ kalẹ̀ lórí Sẹ́nétọ̀ tó lu obìnrin l'Abuja

Oríṣun àwòrán, SenateNGR
Ileegbimọ aṣofin agba lorilẹede Naijiria ti kede pe oun yoo ṣe iwadii ẹsun lilu ọmọbinrin kan nile itaja nilu Abuja eyi ti wọn fi kan Sẹnetọ Elisha Abboni alẹ ọjs iṣẹgun ọjọ keji oṣu keje ọdun 2019.
Nibi ijoko ile naa to waye ni owurọ Ọjọru ni awọn aṣofin naa ti fẹnuko lati wadi ọrọ ọhun nigba ti Sẹnetọ Uba Sani mu wa si etigbọ ile naa lati tete wa nnkan ṣe sii nitori 'iṣẹlẹ naa ti ta ẹrẹ ba aṣọ ala ọpọ awọn aṣofin agba."
Bakan naa ni Sẹnetọ Ọpẹyẹmi Bamidele toun naa da si ijiroro ọhun ni iwa ti Sẹnetọ Abbo hu tapa si abala iwe ofin orilẹede Naijiria.
Amọṣa, olori smọ ẹgbẹ to kere julọ nile naa, Ehinaya Abaribe pẹlu olori ẹgbẹ to pọ julọ nibẹ, Abdullahi Yahaya ko awọn akẹgbẹ wọn ni ijanu lati maṣe da ẹjs lai kọkọ jẹ wi pe wọn tan ina si idi ọrọ naa.
Wọn wa pe fun agbekalẹ igbimọ kan ti yoo wadi ohun gbogbo to rọ ms iṣẹlẹ ọhun.
Ninu ọrọ tirẹ, aarẹ ile aṣofin agba, Ahmed Lawan ṣalaye pe ẹsun ṣi ni ohun gbogbo yoowu ti awọn eeyan ba ri tabi gbọ lori ọrọ naa titi di igba ti ile ba ṣe iwadii ti wọn si fun igun gbogbo ti ọrọ kan ni anfani lati wi tẹnu wọn lori iṣẹlẹ naa.
Sẹnetọ Lawan wa kede igbimọ ti yoo wadii iṣẹlẹ naa labẹ Sẹnetọ Sam Egwu gẹgẹ bii alaga ti Olurẹmi Tinubu, Mathew Rugide, Stellah Uduah, Dauda Haliru Jika, Danladi Sankara ati Mohammed Sani Musa yoo si jẹ ọmọ igbimọ naa.
Ki ni Don Jazzy, MrP, Kate Henshaw àtàwọn èèkàn ìlú míràn sọ lórí Sẹ́nétọ̀ tó lu obìnrin l'Abuja

Oríṣun àwòrán, Don Jazzy
Iwa ipá ninu idile ati lawujọ nilo amojuto lasiko yii.
Awọn wọọ kilu mọ lagbo afẹ lorilẹ-ede Naijiria ti n pe fun fifi ofin gbe sẹnetọ to n ṣoju ẹkun Adamawa North nile aṣofin agba Naijiria naa.
Wọn ni eyi yẹ lori fidio kan to jade ninu eyi ti o ṣafihan sẹnetọ naa to n lu obinrin kan nilu Abuja.
Fidio naa to jade sori ayelujara lọjọ Iṣẹgun fi sẹnetọ Elisha Abbo han nigba to ku giiri si obinrin to ni ṣọọbu itaja eroja adun ibalopọ nilu Abuja to si luu bi ẹni lu bara.
Bi o tilẹ jẹ wi pe Sẹnetọ Abbo sọ pe arabinrin naa yọ ṣuuti ete si oun loun fi luu, awọn eekan bii Don Jazzy atawọn miran ti gba ori oju opo ayelujara lọ lati bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu iwa ti Sẹnetọ naa hu.
Don Jazzy ke si igbakeji aarẹ Osinbajo lati rii pe Sẹnetọ naa ko ṣai jiya iwa to hu yii.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ni tirẹ, Peter Okoye, MrP ti PSquare tẹlẹ ni 'awọn eeyan bii Elisha Abbo ko tọ lati di ipo ilu mu rara' .
O ni afi ki wọn tete fi panpẹ ofin gbe aṣofin naa ni.
Gbajugbaja osere sinima, Kate Henshaw ati onkọrin takasufe, Banky W naa bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu aṣofin naa eleyi to ṣakawe gẹgẹ bii ojuti nla.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2

End of X post, 3
Ariwo ẹhonu lori iwa iṣẹlẹ naa ko mọ lori awọn nnkan ẹka amuludun nikan.
Agba amofin to tun jẹ agbẹnusọ fun ipolongo aarẹ Buhari, Festus Keyamo naa ti pe fun igbesẹ mẹta lati ọdọ awọn ọlọpaa lori ọrọ naa.
"Akọkọ, Ẹ fi panpẹ ofin gbe Ekeji, Ẹ gba ohun rẹ silẹ. Ẹkẹta, Ẹ gbee lọ sile ẹjọ"

Oríṣun àwòrán, Kate Henshaw
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4
Ẹwẹ, agba ọjọgbsn lori ọrọ oṣelu ati imọ ofin, Akin Oyebọde ti ke si igbimọ to n mojuto ẹtọ ati eto nile asofin agba, (Senate Ethics and Privileges Committee) lati tete gbe igbesẹ to tọ lori ọrọ ọhun.