Ọbasanjọ: O dun mi pe awọn obi mi ko ri aseyọri mi

Oloye Olusẹgun Ọbasanjọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọbasanjọ ti jẹ olori ijọba ologun ni Naijiria ri, ko to tun jẹ aarẹ alagbada fun saa meji

Aarẹ ana lorilẹede Naijiria, Oloye olusẹgun Ọbasanjọ ti nfi ika hanu pe bi awọn obi oun ko se pẹ laye lati ri pe oun se aseyọri ndun oun jọjọ.

Ọbasanjọ ni bi o tilẹ jẹpe awọn obi oun jiya pupọ lori oun sibẹ, o ba oun ninujẹ, to si se oun laanu pe wọn ko duro lati foju ri itan aye oun to ja si rere.

Ọbasanjọ fi ika hanu bẹẹ nibi ipejọpọ awọn eeyan nilẹ yi ati loke okun to waa ba se ajọyọ ọjọ ibi ọdun kọkanlelọgọrin rẹ loke eepẹ eyi to waye nile rẹ nilu Abẹokuta.

Ọbasanjọ ni "to ba jẹ pe lootọ lawọn oku maa nriran ri awọn alaaye, ‘awọn obi mi yoo maa fi ẹmi imoore wọn han si awọn eeyan to sisẹ pọ pẹlu mi lati ri pe mo se awọn aseyọri yii’.

Ọbasanjọ tun kabamọ lori ikuna awọn asaaju ni Afrika

"To ba jẹ pe wọn si wa loke eepẹ ni, ori wọn ko ba maa wu nipa awọn aseyọri mi yii ni."

Bakanaa ni Ọbasanjọ tun ge ika jẹ nipa ikuna awọn asaaju nilẹ Naijiria ati nilẹ Afrika, pẹlu afikun pe Ọlọrun ko da ipo ti ko dara mọ ilẹ Naijiria tabi Afrika.