Obasanjo, Fayose ṣe'pade pẹlu aare Buhari l'Abuja

Oríṣun àwòrán, @NGRPresident
Ipade igbimọ olubadamọran to ga julọ lorilẹede Naijiria ti bẹrẹ nilu Abuja, pẹlu aarẹ tẹlẹri Olusẹgun Obasanjọ ati gomina ipinlẹ Ekiti, Ayodele Fayose.
Aarẹ Muhammadu Buhari lo n dari ipade naa eleyi ti yoo jẹ ẹlẹẹkẹta ti aarẹ Buhari yoo maa ko jọ lati ọdun 2015 to ti de ori ipo.

Oríṣun àwòrán, @NGRPresident
Lara awọn to wa nibi ipade naa ni wipe yoo farahan nibi ipade yii ni Oloye Olusegun Obasanjo, gomina ipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayose atawọn gomina ipinlẹ lorilẹede Naijiria.
Bakannaa ni Igbakeji aarẹ, Yemi Osinbajo pẹlu wa nibẹ.

Oríṣun àwòrán, @NGRPresident
Ireti wa wipe awọn wahala ipaniyan awọn darandaran fulani yoo kun ara awọn ohun ti ireti wa wipe yoo wa fun ijiroro nibi ipade naa.
Ẹkunrẹrẹ iroyin n bọ laipẹ.








