Twins Festival: Asọ ń pe asọ ránsẹ́ lára àwọn ìbejì lásìkò ọdún wọn

Ẹsẹ̀ kò gbèrò ní ìlú Igbo ọrà lásìkò ọdún ìbejì àgbáyé tí ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ sètò.

Awọn ibeji ni Igbo Ọra
Àkọlé àwòrán, Ọdun ibeji agbaye sọkutu wọwọ ni ilu Igbo Ọra
Awọn ibeji ni Igbo Ọra
Àkọlé àwòrán, Ati agba ibeji, ati ọmọde ibeji ko gbẹ́yin nibi ọdun ibeji ni Igbo Ọra
Awọn ibeji ni Igbo Ọra
Àkọlé àwòrán, ijo ree lẹsẹ awọn ibeji, ti kọmisọna feto iroyin nipinlẹ Ọyọ, Toye Arulogun si n kọwọ rin pẹlu wọn
Awọn ibeji ni Igbo Ọra
Àkọlé àwòrán, Ankoo wa laa wọ lawọn ibeji yii se nibi ajọdun wọn ni Igbo Ọra
Awọn ibeji ni Igbo Ọra
Àkọlé àwòrán, Kọmisọna ree to n bawọn ibeji ya fọto nibi ajọdun ibeji Igbo Ọra
Awọn ibeji ni Igbo Ọra
Àkọlé àwòrán, Ajọdun ibeji agbaye yii ko yọ ẹlẹsin abi ọdọ silẹ, tọkunrin, tobinrin lo wa nibẹ
Awọn ibeji ni Igbo Ọra
Àkọlé àwòrán, Eyi wu wa o, awọn ọmọge ibeji ree o, ti wọn fi ilẹkẹ sọrun
Awọn ibeji ni Igbo Ọra
Àkọlé àwòrán, Ọmọde n bọ wa dagba, bi ẹyin ti n di akukọ. Awọn agba ibeji naa ree
Awọn ibeji ni Igbo Ọra
Àkọlé àwòrán, Awọn ibeji to ni ‘swagger‘ ree o, wọn ta san-san
Awọn ibeji ni Igbo Ọra
Àkọlé àwòrán, N jẹ ẹyin mọ iyatọ laarin awọn ibeji yii? N se ni wọn jọ ara wọn bii imumu
Awọn ibeji ni Igbo Ọra
Àkọlé àwòrán, Ọlọrun ma pa ibeji mi fun mi, ni adura ti baba yii n se lasiko to n bawọn ibeji rẹ ya fọto
Awọn ibeji ni Igbo Ọra
Àkọlé àwòrán, Awọn ibeji yii ma wu ni o, ejirẹ ara isokun
Awọn ibeji ni Igbo Ọra
Àkọlé àwòrán, Asọ kan naa, awọ kan naa, ila kan naa, koda, bakan naa ni awọn ibeji yii n wo. Ọlọrun ku isẹ rẹ
Awọn ibeji ni Igbo Ọra
Àkọlé àwòrán, Ẹni maa bi ibeji ko sẹwa wa, ọdun ibeji ko yọ awọn ibeji ọmọ ọwọ silẹ ni Igbo Ọra
Awọn ibeji ni Igbo Ọra
Àkọlé àwòrán, O ga ju. Ibeji alakọ lawọn eleyii. Ọlọrun ko ni pa yin fun wa
Awọn ibeji ni Igbo Ọra
Àkọlé àwòrán, Se ibeji ọmọ-ọba lawọn ibeji yii ni? Ilẹkẹ ọrun wọn gan n da ni lọrun
Awọn ibeji ni Igbo Ọra
Àkọlé àwòrán, Ọdun ibeji yii ko yọ awọn agba ibeji silẹ, a kii saa dagba ‘Malabẹ, eegun ẹran la le fọ’