Senator Elisha Abbo: Ọga àgbà ọlọ́pàá Nàìjíríà ti pàṣẹ ìwádìí sí ọ̀rọ̀ Sẹ́nétọ̀ Abbo tó lu obìnrin l'Abuja

Oríṣun àwòrán, @adeyanjudeji
Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹ-ede Naijiria ti ni ko si igba kankan ti àwọn paṣẹ mimu Seneto Abbo.
O ni ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa, Mohammed Adamu kò paṣẹ ki wọn mu Sẹnetọ Abbo ti iroyin n ja ranyinranyin pe o lu obinrin kan nilee itaja nilu Abuja.
Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, alukoro agba fun ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹ-ede Naijiria, Frank Mba ni ọga agba ọlọpaa ti paṣẹ pe ki iwadii to rinlẹ o bẹrẹ ni pẹrẹu lori iṣẹlẹ naa.
O ni eyi ko fi ọna kankan jẹ mọ pe wọn mu aṣofin agba naa.
Ọjọ Iṣẹgun ni fidio kan jade to ṣafihan bi Sẹnetọ naa ṣe n lu obinrin kan nile itaja eroja ibalopọ
Ọgbẹni Frank Mba ni awọn ọlọpaa ti kan si arabinrin ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si pẹlu awọn igun miran ti ọrọ kan igbesẹ iwadii si n lọ .
Deji Adeyanju àtàwọn mìí tí mú ìwé ẹ̀sùn dé iléèṣẹ́ ọlọ́pàá lórí ọ̀rọ̀ Elisha Abbo

Oríṣun àwòrán, Elisha Ishaku abbo
Ajafẹtọ ọmọniyan kan l'orilẹede Naijiria, Comrade Deji Adeyanju kede lọjọ Iṣẹgun pe oun yoo ko awọn eniyan jọ lori ọrọ yii.
O ni awọn yoo si jọ wọde lọ si ọọfisi Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa, lati fun un ni iwe ẹsun lori ọrọ Sẹnetọ Elisha Abbo ti wọn lo lu arabinrin kan nile itaja kan ibalopọ l'Abuja.
Nibayii, awọ̀n olufẹ̀honu han naa ti wa ni ọọfisi ọga agba ọlọpaa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ọjọ Iṣẹgun ni iwe iroyin ori ayelujara, Premium Times fi fidio kan sita, to ṣafihan bi Sẹnetọ naa, to jẹ pe oun lọjọ ori rẹ kere ju nile aṣofin agba Naijiria, ṣe n lu obinrin kan nile itaja eroja ibalopọ.
Ọpọ lo si ti n koro oju, bu ẹnu ẹtẹ lu ihuwasi sẹnetọ naa.
Ṣugbọn nigba ti yoo fesi, Sẹnetọ Abbo sọ fun BBC pe, oun ko mọọmọ lu obinrin naa.
Koda, ajọ ajafẹtọ ọmọniyan l'agbaye, Amnesty International ti dasi ọrọ naa, to si ti kesi ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria lati wadii rẹ.
'Awọn to wa ninu ile itaja naa lo kọkọ lu aburo mi bolẹ, ti wọn si gba ẹjẹ lẹnu rẹ ni emi ṣe lu awọn naa bolẹ.''
















