LASEMA Lagos Accident: Ọkọ̀ akóyanrìn tẹ èèyàn kan pa ní Epe

Oríṣun àwòrán, Lasema/Facebook
Ijamba ọkọ kan to waye lagbegbe oju ọna marosẹ Lekki si Epe ti ran eeyan kan lọ sọrun
Gẹgẹ bi atẹjade kan ti ajọ LASEMA fi sita, wọn doola ẹmi eeyan kan bẹẹ ni wọn gbe oku eeyan miran kan jade nibi ijamba naa.
Ijamba ọkọ naa kan ọkọ ayọkẹlẹ Camry kan ti nọmba rẹ jẹ KSF920 FF ti ọkọ akoyanrin tioa kan ti nọmba rẹ jẹ ENU 576 ZZ to ko okuta lọ rọ lu to si tẹ mọlẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Àlàyé rèé lórí bí mo ṣe fi ọsàn híhó fẹ́ ìyàwó mi"
- Ọwọ́ tẹ ọkùnrin kan ní pápákọ̀ òfurufú l‘Eko tó ń kó ike ATM 2,886 lọ si Dubai
- Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, ìjọba Kwara fẹ́ sọ orúkọ Rashidi Yẹkini di mánigbàgbé
- Ọ̀kẹ àìmọye ẹ̀rọ àyẹ̀wò káàdì olùdìbò jóná mọ́lé l' Ondo
- Wo iye àwọn tó ti gbẹ̀mí ara wọn ní Nàìjíríà láàrin ọdún mẹ́rin ìjọba Buhari
Lagbegbe Alasia bus stop ni Marosẹ Lekki si Epẹ; Ajọ LASEMA si jẹ ko di mimọ pe ijanu ọkọ akoyanrin lo sọ iṣẹ silẹ ti fi lọ kọlu ọkọ ayọkẹlẹ naa to si tẹ awakọ rẹ pa.
Eeyan meji lo wa ninu ọkọ ayọkẹlẹ naa nigba ti ijamba naa ti waye, eeyan kan ku, eeyan kan yoku si n gba itọju
Ọkọ̀ tírélà 3 kọlu ọkọ̀ ìgboro, obìrin 2 kú, 6 farapa yánnayànna

Oríṣun àwòrán, Lasema/Facebook
Awọn obinrin meji to wa ninu ọkọ igboro ti padanu ẹmi wọn lasiko ti ijamba ọkọ waye ni agbegbe Anthony to wọ Gbagada ni ipinlẹ Eko.
Ọkọ tirela mẹta lo fa ijamba ọkọ naa lẹyin ti wọn kọlu ọkọ igboro to gbe awọn eniyan, eleyii ti ọmọ kekere kan wa ninu ọkọ naa.
Ajọ oṣiṣẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko, LASEMA fi iroyin ijamba ọkọ to waye ni alẹ Ọjọ Iṣẹgun naa lede ni oju opo ikansiraẹni Facebook wọn.
Ajọ LASEMA ni ọkọ tipper mẹta lo lọ run ọkọ akero igboro mọlẹ pẹlu awọn ẹrọ to wa ninu ọkọ naa.
- Ìjàmbá ọkọ̀ tó ṣẹlẹ̀ sí Adams Oshiomole kìí ṣe ojú lásan, àwọn kan ló fẹ́ pa á- APC
- Ọba Saudi Arabia yọ ọmọ rẹ̀ àti àbúrò rẹ̀ kúrò nípò nítorí ìwà àjẹbánu lórí owó tó yẹ fún ààbò ìlú
- Èèyàn 239 míràn ṣẹ̀ṣẹ̀ kó COVID-19 ní Nàìjíríà
- Ọkùnrin kan di èrò ọ̀run nítorí pé o fi ẹ̀sùn kan alájọgbélé rẹ̀ pé o n yan ìyàwó ẹnìkan lálè
- Victoria Rubadir ọmọ Kenya ló gba àmì ẹ̀yẹ Komla Dumor BBC World News

Oríṣun àwòrán, Lasema/Facebook
Wọn ni awọn doola ẹmi eniyan meje, agbalagba mẹfa ati ọmọde kan, ti wọn si farapa
Amọ, awọn obinrin agbalagba meji sọ ẹmi wọn nu ninu ijamba ọkọ naa.
Ajọ LASEMA ni awọn ṣiṣẹ lati alẹ Ọjọ Iṣẹgun ti ijamba ọkọ naa ti waye, titi di owurọ ọjọ keji.

Oríṣun àwòrán, Lasema/Facebook
Adari ikọ LASEMA, Olufemi Oke-Osanyintolu lasiko to n ba awọn ẹbi ati ara awọn ti ijamba ọkọ naa kẹdun, parọwa si awọn eniyan lati ṣọra ṣe loju popo.
- Àwọn ará ìlú Ikarẹ Akoko ń ṣọ̀fọ̀ Ọba Adegbite, Ọwá Ale Ikarẹ tó wàjà
- Gbajúgbajà òṣèré “Blue film'' wọ gàù ẹ̀sùn fífipá bá obìrin 13 lòpọ̀
- Ẹgbẹ́ wa ò dàrú o! Kódà gbọingbọin la wà lẹ́yìn Akintoye gẹ́gẹ́ bíi adarí YWC nílé, lẹ́yìn odi
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Kogi kéde ọjọ́ ìwọlé àwọn akẹ́kọ̀ọ́
- Àṣírí tú! Wo àwọn tó ń jí owó Covid-19 tí Ìjọba ní wọ́n yóò káwọ́ pọ̀nyìn rojọ́
Ajọ pajawiri ni ipinlẹ Eko, LASEMA naa fikun un pe awọn awakọ loju popo, paapaa tirela gbọdọ ma a wakọ jẹjẹ loju popo, ki wọn si ye sare asapajude.
Ki lo ti kọkọ ṣẹlẹ ni Eko gẹgẹ bii ijamba?
Ọ̀kọ̀ ojú omi dànù, ènìyàn méjì kù, ẹnìkan di àwátì
Ọkọ oju omi to danu ti mu ẹmi eniyan meji lọ ti eniyan kan si ti awati.
Ninu atẹjade ti adari ileeṣẹ Lagos State Waterways Authority (LASWA), Oluwadamilola Emmanuel lo fi iroyin naa lede bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Emmanuel ni ọkọ oju omi naa n lọ lati Makoko pẹlu awọn eniyan mẹje ninu rẹ, awọn marun un jẹ agbalagba nigba ti awọn ọmọde meji wa nibẹ pẹlu awakọ naa.
Ọkọ oju omi naa n lọ si Ikorodu ni ibi ti wọn ti fẹ lọ ṣeto isinku mọlẹbi wọn, ko to di wi pe iṣẹlẹ naa waye to si mu ẹmi eniyan meji lọ.
Ajọ LASWA fi lede wi pe awọn doola ẹmi awọn eniyan mẹrin, amọ awọn ṣi n wa ẹnikan to ku nigba ti iṣẹlẹ ọkọ oju omi naa waye.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Wọn ni ohun to fa iṣẹlẹ naa ni wi pe ọkọ oju omi gbe ju iye eniyan to yẹ lọ, ti iji si bẹ silẹ laarin omi naa.
Bakan naa ni wọn fikun wi pe awọn to wa ninu ọkọ naa pẹlu awakọ oju omi naa ko wọ asọ ti kii muni ri sinu omi( life jacket) lasiko ti wọn fi wa lori omi.
- Victoria Rubadir ọmọ Kenya ló gba àmì ẹ̀yẹ Komla Dumor BBC World News.
- Ohun tí a mọ̀ nìyí nípa gbọ́nmi síi omi ò tó lórí ọ̀rọ̀ oyè Babaloja-General ní ìpínlẹ̀ Oyo
- Ìpínlẹ̀ Osun kéde ọjọ́ táwọn iléèwé yóò ṣí padà
- YWC yọ Ààrẹ Banji Akintoye nípò àbi Akintoye tú ìgbìmọ̀ aláṣẹ YWC ká
- Wo àwọn orílẹ́-èdè mẹ́wàá tí kò ní coronavirus lágbàáyé, bá wo ni wọ́n ṣe ṣe é?
- Máa gbé kẹ̀kẹ́ rẹ lọ, àwọn akọròyìn kọ̀ ìpàkọ́ sí Femi Fani Kayọde
Nibayii, awọn ọlọpaa to n ṣiṣẹ loju omi ati Ajọ oṣiṣẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko, Lasema n ṣiṣẹ papọ lọna ati sawari ẹni to sọnu ninu ijamba ọkọ naa.
Bakan naa ni wọn fikun wi pe iwadii ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ naa.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Torí ₦300, awakọ̀ ojú omi ṣokùnfà ikú èèyàn méjìlá l'Eko - Ọlọ́pàá
Kọmisọna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu ti foju awakọ oju omi Bimbo Elebiju han pe oun lo dẹmi awọn eniyan legbodo.
Wọn ni oun lo fa iku eniyan mejila lasiko to n gbe wọn lọ si ibudo wọn losu to kọja.

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Awọn eniyan yii se kongẹ iku nipa bi wọn se ri somi lagbegbe Kirikiri, lẹyin ti ọwọja omi dari ọkọ lọ soju omi to jẹ dagun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Inú mí dùn láti kọrin pẹlú Beyonce nílẹ̀ Amerika- Ìyá àgbà láti Nàíjíríà
- Àwọn òṣèré tíátà Yorùbá kọjú ìjà síra wọn lórí ìdárò akẹẹgbẹ́ wọn tó kú
- Ìpàkọ́ kò gbọ́ sùtì ní ọ̀rọ̀ ẹ̀yin tí ẹ̀ ń bú mi- Oyedepo
- Mo kọ̀ láti pín ọkọ mi pẹ̀lú ẹnikẹ́ni, nítorí náà ẹ tú wa ká- Abílékọ Idowu faraya ní kóòtù kọkọ-kọkọ
- Walter Carrington ràn mí lọ́wọ́ kí ń lè sá àsálà lásìkò tí Abacha ń wá mí kiri- Obasanjo
- Kíákíá lọ daṣọ bo igbá àyà rẹ to ṣí kalẹ̀! -Big Brother sọ fún Dorathy
Eyi ni wọn lo waye leyin ti awakọ pa ina ọkọ oju omi nibi to ti n se ariyanjiyan pẹlu awọn ero ọkọ lori iye owo ti yoo gba.
Odumosu, lasiko to gbe Bimbo sita fun ifọrọwanilẹnuwo ni olu ile isẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko to wa ni Ikeja, ni ogun eniyan lo wọkọ oju omi naa lati Kirikiri.

Oríṣun àwòrán, @lasemasocial
O ni wọn n lọ si Badagry, sugbọn bi wọn ṣe n lọ, ọkan ninu awọn ero ọkọ tako iye ti awakọ pe owo ọkọ.
Odumosu ni awakọ ni ẹgbẹrun kan aabọ naira ni oun yoo gba, nigba ti ero ọkọ yari si ẹgbẹfa naira, eyi si lo mu ki awakọ pana ọkọ lagbegbe lori omi nitori iyatọ ọọdunrun naira.
Bakan naa lo fi kun pe, nigba ti Bimbo ri pe atẹgun ti gba ọkọ lọwọ oun, lo ba bẹ sinu omi, to si fi gbogbo awọn ero kalẹ, ti wọn si ri somi.
Odumosu ni awọn ero ọkọ mejila ri somi, nigba ti wọn ri awọn marun yọ, awọn ti ori ko yọ yii lo salaye nnkan to ṣẹlẹ si wọn, ati nnkan ti Bimbo se.

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Ọga ọlọpaa ni, awọn tọpasẹ awakọ naa ni awọn fi ri mu, sugbọn awọn yoo gbe lọ si ile ẹjọ laipẹ.
Odumosu ni iṣẹlẹ naa waye ni ọjọ kọkandinlọgbọn, osu keje ọdun yii.
"Ni nkan bi aago mẹfa ku iṣẹju mẹẹdogun ni awọn ọlọpaa to n bojuto oju omi gba ipe ijaya pe ọkọ oju omi akero Mount Zion transport ti n ri somi oo, to si gbe ogun ero lati Badagry.
Titi di asiko yii, eniyan marun ni wọn ri yọ laaye, eniyan mejila ku nigba ti ko si ẹni to ri awọn eniyan mẹta to ku.
Èèyàn 7 kú, 21 di àwátì lásìkò tí ọkọ̀ ojú omi dojúdé ní Eko àti Benue

Oríṣun àwòrán, @lasemasocial
Ajọ oṣiṣẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko, LASEMA ti fi lede pe eniyan meje lo sọ ẹmi wọn nu lẹyin ti ọkọ oju omi danu ni opin ọsẹ.
Oludari Ajọ LASEMA ni ipinlẹ Eko, Olufemi Oke-Osanyintolu ninu atẹjade to fi sita ni, ijamba ọkọ oju omi naa waye nitori wọn rin lasiko ti okunkun ti ṣu, eleyii to tako ofin irinna ọkọ loju omi.
Bakan naa lo fikun pe, lara awọn eniyan naa ko wọ aṣọ idaabobo loju omi (life jacket) eleyii to ni o ṣe akoba fun wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Bí Hushpuppi ṣe tiraka rèé l‘Eko, kí ọlà ‘òjijì’ tó dé
- Akẹ́kọ̀ọ́ wọlé padà, ìjọba Oyo kò pèsè ìbòmú lòdì sí ìlérí rẹ̀
- Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ òṣèlú, ẹ̀sìn àti ẹ̀yà ṣe fa ogun abẹ́lé Biafra
- Kàkà k‘éwé àgbọn dẹ̀ lágbo òṣèlú l‘Ondo, akọ̀wé ìjọba tún kọ̀wé fipò sílẹ̀
- Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ òṣèlú, ẹ̀sìn àti ẹ̀yà ṣe fa ogun abẹ́lé Biafra
Oke-Osanyintolu ni eniyan mẹtalelogun lo wa ninu ọkọ oju omi naa, ko to yi danu.
O ni eeyan mẹrindinlogun ni awọn ri yọ kuro ninu omi, nigba ti awọn meje to jẹ kiki obinrin padanu ẹmi wọn.
Oludari Ajo LASEMA naa wa parọwa si awọn eniyan lati ri pe wọn tẹle ofin irinna ọkọ oju omi ati lilo aṣọ idaabobo, nigba kugba ti wọn ba wa loju omi.
Ẹwẹ, o kere tan eniyan mọkanlelogun ni wọn si n wa lẹyin ijamba ọkọ oju omi ni ipinlẹ Benue.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn mẹtalelogun ni wọn wa ninu ọkọ oju omi naa, ti wọn si ti doola ẹmi awọn meji ninu wọn.
Awọn ti iṣẹlẹ naa soju wọn ni ohun to sokunfa ijamba ọkọ oju omi naa ni pe awọn eniyan to wa ninu ọkọ oju omi naa pọ ju bo ṣe yẹ lọ.
Wọn fikun wi pe awọn to wa ninu ọkọ naa n lọ si ipagọ awọn ẹlẹsin Kristẹni, ki iṣẹlẹ naa to waye
Òkú èèyàn mẹ́jọ ni wọ́n yọ níbi ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá ọkọ̀ nílùú Eko lọ́jọ́ Aje
Oku eeyan mẹjọ ni wọn ti yọ jade ninu omi bayii nibi ijamba ọkọ oju omi kan to waye ni ọjọ Satide.
Eeyan mọkanlelogun lo wa ninu ọkọ naa lasiko to fi ri sinu agbami 'Èèyàn mi mẹ́ta ló wà nínú ọkọ̀ ojú omi tó dà nù l'Eko!'.
Ilu Ikorodu ni ọkọ naa morile lati agbegbe Ajah lasiko ti ijamba naa fi ṣẹlẹ.
Gẹgẹ bii atẹjade kan ti Ọga agba ajọ to n moju to iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko LASEMA, Ọmọwe Oluwafẹmi Oke-Ọsanyintolu fi sita, o ni oku eeyan mẹjọ ni wọn ti fa jade ninu agbami bayii.
Meje ninu awọn ti wọn ti fi idi iku wọn mulẹ naa lo jẹ Ọkunrin ti ọkan si jẹ obinrin.
Bakan naa lo ṣalaye pe ni kete ti ijamba naa ti waye ni wọn ti doola ẹmi awọn mẹta ninu awọn ero ti ọkọ naa da somi.
Ọga agba ajọ LASEMA naa ṣalaye pe eto wiwa awọn to ku ninu agbami ṣi n tẹ siwaju.
O ni ajọṣepọ laarin LASEMA, ileeṣẹ irinna oju omi nipinlẹ Eko, ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ori omi, ileeṣẹ ọlọpaa oriilẹ, ileeṣẹ panapana pẹlu awọn omuwẹ lagbegbe naa ni iṣẹ awari awọn eeyan to da somi naa jẹ.
Iroyin ti ileeṣẹ wa gbọ tun fi kun un pe yatọ si eeyan mẹjọ ti awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi gbe oku wọn jade yii, oku eeyan meje ni wọn ti kọkọ yọ jade ni alẹ ọjọ Satide ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

















