Lagos Theft: Ẹrù olè gbé ẹ̀ṣọ́ ilé wọ kóló olọ́pàá

Awọn afẹsunkan ti RRS mu tori simẹnti

Oríṣun àwòrán, RRS

Ikọ kogberegbe ti ileeṣẹ Ipinlẹ Eko (RRS) ti mu awakọ kan ti wọn fẹsun kan wi pe o ra ẹru ole - awọn nkan ikọle ti awọn oṣiṣẹ kan maa n ji ni agbegbe Lekki.

Atẹjade RRS kan ni ọwọ tẹ afẹsunkan naa Hassan Abubakar ẹni ọdun mejilelọgbọn nigba to n wa ọkọ akẹru kan to fi ko apo simẹnti mọkanlelogun ni bi aago marun aabọ aarọ nigba ti awọn n kaakiri adugbo naa.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Ṣugbọn nigba ti wọn pe ẹni to sọ pe o ran oun niṣẹ, Abubakar bẹrẹ si ni ka bi ẹyẹ. O ni ọkan lara wọn ọdẹ to n ṣọ ibi ti wọn ti n kọ ile naa, Adamu Ibrahim lo ji simẹnti naa.

Nigba ti ọwọ ba Adamu, o ni ẹni to ni ile ti wọn n kọ na jẹ oun ni ẹgbẹrun marundinlọgbọ owo oṣu. O ni owo naa ni oun fẹ gba pada ti oun fi ko awọn simẹnti naa.

RRS ni wọn ti fa awọn afẹsun kan naa le ẹka to n ṣe iwadii awọn ẹsun ni Ipinlẹ eko (SCID) lọwọ fun iwadii.

Àkọlé fídíò, Ijinigbe: BBC ṣe ìwádìí bí ikọ̀ IRT ṣe ń gbéjà ko awọn ajinigbe lójú