Oyo traders crisis: Ẹgbẹ́ oníṣòwò ṣèwọ́de lórí ìyànsípò YK Abass gẹ́gẹ́ bí bàbálọ́jà tuntun

Iyaloja

Oríṣun àwòrán, others

Awọn oniṣowo labẹ asia ẹgbẹ Coalition of Market Groups of Oyo State ṣe iwọde lati tako bi Olubadan ti ilẹ Ibadan, Oba Saliu Adetunji ti yan Ọgbẹni Yekini Abass gẹgẹ bi Babalọja gbogbogbo ipinlẹ Oyo.

Ẹgbẹ́ oníṣòwò ṣèwọ́de lórí ìyànsípò YK Abass gẹ́gẹ́ bí bàbálọ́jà tuntun pe meloo ni awọn wa fẹ ni gẹgẹ bii Babalọja.

Wọn ni babalọja marun un nipinlẹ Oyo yoo ni ti Gomina Seyi Makinde ba fi le buwọlu iyansipo YK Abass.

Ohun tí wọn n sọ nipe niṣe ni Olubadan kan gbe Ọgbẹni Abass le awọn lori.

Bi ẹ ko ba gbagbe, oṣu to lọ ni Olubadan yan YK Abass gẹgẹ bi Babalọja gbogbogbo tuntun nipinlẹ Oyo.

Àkọlé fídíò, Mayowa Omoniyi: Kò sí orin Obey, Sunny Ade abí tàkasúfèé tí ń kò le ta gìtá sí

Awọn olufẹhonuhan naa to lọ si ọfiisi ẹgbẹ awọn akọroyin ni Ibadan sọ pe yiyan babalọja kii ṣee ojuṣe Olubadan.

Wọn ni oye Babalọja kii ṣee fun ilu Ibadan nikan, gbogbo ipinlẹ Oyo lo wà fún.

Awọn oniṣowo ọhun lawọn ti bẹrẹ sí ni gbe igbesẹ lati yan Babalọja tuntun ki Olubadan to Kede YK Abass gẹgẹ bí babalọja tuntun.

Maki

Oríṣun àwòrán, Others

Bí ìjà bá wà láàrin èmi àti Olubadan, a ó yanjú ẹ ní pẹ̀lẹ́kùtù, ọ̀rọ̀ bàbálọ́jà kò lè dìjà

Ṣeyi Makinde ṣàbẹ̀wò s'áàfin Olubadan, Ó ní tùbí ǹ nùbí ni ọ̀rọ̀ gbà

Bi ija ba wa laarin emi ati Olubadan, a o yanju ọrọ ni pẹlẹkutu- Makinde

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC: Mọ̀ si nípa oríṣìí ẹ̀ka ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ àti ìwúlò wọn

Gomina ipinlẹ Oyo onimọ ẹrọ Seyi Makinde sabẹwo si aafin Olubadan ti ilu Ibadan, Ọba Saliu Adetunji, Ajenigunuso, nibi to ti tun fidi rẹ mulẹ pe oun ko ni fori ade wọlẹ ati pe gbogbo ọwọ to tọ si wọn l'oun yoo ma fi wọ wọn.

Eyi jẹyọ lasiko to lọ ki oriade laafin fun ti ayẹyẹ ayajọ ọjọ ibi ọdun mejilelaadọrun.

O ni oun lo fun iṣẹ ẹgbẹ oselu PDP ni ipinlẹ Ondo, sugbọn oun fun ori ade ni atilẹyin lati yan Babalọja Ìpínlẹ̀ Oyọ.

Àkọlé fídíò, Bolaji Faleke ni Olùkọ́ tó ń kọ́ wa ní àṣà oge ṣiṣe lórí BBC Yorùbá

Gẹgẹ bi o ṣe sọ, ijọba oun yoo sa gbogbo ipa rẹ lati fun awọn ori ade ipinlẹ naa ni aaye lati ṣe nkan to ba wu wọn to si mu idẹrun ba ara ilu, ati pe ẹni a bi ire ni oun oun ko le fi awọn agba wọlẹ.

Ninu atẹjade kan ti akowe iroyin Gomina Taiwo Adisa fowosi, ni gomina ti rọ ara ilu lati ni ifọwọsowọpọ pẹlu oun lati mu ilọsiwaju ba ipinlẹ Oyo.

O ni iṣẹ ati oṣi ko mọ Musulumi abi Kritẹni, nitori naa ki ara ilu maa fi aaye gba awọn ti wọn maa n fi ẹsin da ilu ru lati da isọkan ipinlẹ Oyo ru.

Àkọlé fídíò, Baby abandoned on dunmpsite: Mo ti bímọ mẹ́rin tẹ́lẹ̀ fún bàbá méjì nínú òṣí- Dupe Ogbomos

Makinde ni wiwa ti oun wa si aafin ni lati fihan fun awọn oni gboyi sọyi to sọ pe nitori ija to wa laarin oun ati Kabiyesi ni oun ko fi yoju sibi ayẹyẹ ọjọ ibi Kabiyesi.

"Ko si ija laarin wa ti a ba si ri ede aiyede kan ao pari rẹ ni tubi n nibi ni, gẹgẹ bi baba ati ọmọ.

O ni" fun gbogbo awọn to n polongo ijọba ipinlẹ Oyo kiri pe ija wa laarin oun ati Olubadan, ẹ jẹ ki n sọ fun yin, ile ire ni a ti bi mi, mi o si ni tẹ asọ agba mọlẹ.

Gbogbo ẹni to ba di gomina lọla ki o tete mọ pe ọdun mẹrin pere ni, ti o ba wa wu lati lọ lẹẹkan si, o ni lati pada wa si ọdō awọn eniyan lati sọ fun wọn. "

Àkọlé fídíò, Bí ẹ ṣe mọ̀wé tó, ẹ wá dánrawò níbí pẹ̀lú "Àpólà Ọ̀rọ̀ Orúkọ - Noun Phrase

Makinde ni " Bi awọn eniyan ba wa fẹ wọn o dibo fun, bi wọn o ba si fẹ, sugbọn ni ti Ọba, ọjọ to ba ti gori oye, o di igba to ba wọ aja lọ ba awọn baba rẹ, nitori naa, ko si nkan to le maa fa ija laarin oun ati Kabiyesi"

"Mo tun fẹ fi da a yin loju lẹẹkan si pe, a o se gbogbo nkan ti o yẹ ka ṣe bi ijọba, kii se fun Olubadan nikan bikose se gbogbo awọn lọbalọba to ku nipinlẹ Oyo.

A maa fun wọn ni ọwọ ti wọn, a maa se nkan to tọ si wọn, ti gbonmisi-omi o to ba si wa baba le pe mi a o si yanju rẹ ni pẹlẹpẹlẹ"

Olubadan pẹlu Alhaji YK Abass ati Iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, Nigerian Tribune

Ohun tí a mọ̀ nìyí nípa gbọ́nmi síi omi ò tó lórí ọ̀rọ̀ oyè Babaloja-General ní ìpínlẹ̀ Oyo

Kí ló ń fa gbọ́nmi síi omi ò tó lórí ọ̀rọ̀ oyè Babaloja-General ní ìpínlẹ̀ Oyo?

Omi alaafia n fẹ maa daru lẹgbẹ awọn iyalọja ati babalọja ni ipinlẹ Ọyọ lori tani yoo jẹ oye Babalọja agba, iyẹn babalọja general fawọn ọlọja ni ipinlẹ Ọyọ.

Àkọlé fídíò, Natalia Mufuta ìyá Yakub, Kamil àti Adam sọ̀rọ̀ lórí bí wọ́n ń sọ èdè mẹ́rin pàpọ

Lootọ, ni ọjọ Ẹti ni iroyin kan jade pe Olubadan ti ilẹ Ibadan, Ọba Adetunji ti fi Alhaji Yekeen Abass ti ọpọ mọ si YK Abass, baba alaṣọ ni Gbagi ni ilu Ibadan jẹ ni aafin olubadan.

Ṣaaju ni ọjọ Aje, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2020 ni wọn ti fi Alhaji Aderẹmi Jimoh jẹ oye babalọja gẹneral kan naa ni gbọngan awọn lọbalọba ipinlẹ Ọyọ.

Pẹlu bi ọrọ ṣe jẹ yii, rukerudo ati edeaiyede lo ti n waye lori pe ta gan an wa ni Babalọja tootọ ni ipinlẹ Ọyọ o?

Ọja kan nilu Ibadan

Oríṣun àwòrán, others

Ki ni Alhaji Aderẹmi Jimoh duro le?

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, Alhaji Aderẹmi Jimọh ṣalaye pe ko si igba kan ninu itan oye Babalọja general ni ipinlẹ Ọyọ jijẹ ti oye naa wa lati ọdọ balaye kankan ni ipinlẹ Ọyọ, bẹẹni ko si eyikeyi ti wọn jẹ ni aafin ọba.

O fi kun un pe ninu awọn meji to ti jẹ oye naa ṣaaju, iyẹn Oloye Amubikahun, Oloye Ladapọ to jade laye ni oṣu kẹfa, ọdun 2020, ijọba ipinlẹ Ọyọ lo maa n ṣe agbatẹru rẹ.

Alhaji Aderẹmi Jimoh ṣalaye pe awọn ọlọja lo fa oun kalẹ fun igbimọ majẹobajẹ awọn ọlọja ni ipinlẹ Ọyọ ati pe awọn igbimọ ọlọja naa lo fa oun le ijọba ipinlẹ Ọyọ lọwọ.

ja Sango Oju-Irin

Oríṣun àwòrán, Ibadan city announcer/ twitter

Ki ni Aafin Olubadan sọ?

Amọṣa ninu ọrọ tirẹ, olubadan ti ilẹ Ibadan, Ọba Saliu Adetunji ṣalaye pe, oye onilẹkẹ ni oye Babalọja-General, nitori naa ọba lo laṣẹ lati fi eeyan jẹ.

Kabiyesi Olubadan to gba ẹnu agbẹnusọ rẹ, alagba Deọla Ọlọkọ sọrọ ṣalaye pe lootọ awọn meji to jẹ ṣaaju ko gba ọdọ awọn ọba jẹ, sibẹ wọn pada wa to o lọna to tọ lọdọ awọn Ọbalaye naa.

O ni ṣaaju ajakalẹ arun COVID-19 ni iwe ififẹhan si ipo naa ti jade wa lati ọdọ Alhaji YK Abass ti wọn si ti fun wọn ni aaye oṣu mẹrin boya iwe yoo wa lati ọdọ ẹlomiran leyi ti ko wa.

Ọja kan nilu Ibadan

Oríṣun àwòrán, others

O fi kun un pe igbesẹ ni ti Olubadan to jawe oye le e lori ati pe yoo ṣi tọ awọn Ọbalaye yoku ni ipinlẹ Ọyọ lọ fun igbọwọle tiwọn naa.

Gbogbo akitiyan lati kan si ijọba ipinlẹ Ọyọ nipasẹ kọmiṣọnna fun eto katakara lo ja si pabo .

Bakan naa ni a gbiyanju lati kan si Alhaji YK Abass ti Olubadan fi jẹ, ṣugbọn awọn naa ni awọn ko lee raye sọrs bayii.

Ṣugbọn pẹlu bi ọrọ ṣe ri bayii, adiyẹ balokun lọrọ oye Babalọja gẹneral ni ipinlẹ Ọyọ bayii nitori omi alaafia aarin awọn ọlọja naa ko fẹ gun.

Àkọlé fídíò, Wo bí Sunday Orimola ṣe gba ikú ẹranko kú ní Ifon ni Ondo lórí ọ̀nà àtijẹ