Cameroon Atrocity, BBC Africa Eye: Ẹwọ́n ọdún méjìlá ni wọ́n fún àwọn sója mẹ́rin tó pa ìyá àti ọmọ méjì ní Cameroon

Àwọn ọmọ ogun orilẹ̀-èdè Cameroon mẹ́rìn ni wọ́n ti dájọ ẹ̀wọ̀n ọdún méjìlá fún, wọ́n jẹ̀bi ìpànìyàn lásìkò ti wọ́n ń ja ìjà àwọn agbésùmọmí lórílẹ̀-èdè náà.
Wọ́n ní àwọn sójà yìí ló pa obìnrin kan àti àwọn ọmọ rẹ̀ méjì ní orílẹ̀-èdè Cameroon.
Èyí jẹyọ nínú fọ́ran kan tó jẹyọ lórí ayélujara nínú oṣù kéje ọdún 2018 níbi ti àwọn ọmọ ogun kan ti daṣọ bo awọn obinrin meji lójú pẹ̀lú ọmọbinrin lórí ìkúnlẹ̀ ti wọ́n sì pọ ọmọ sẹ́yìn.
Bótilẹ̀ jẹ́ pé ìjọba kọ́kọ́ sọ pé kìí ṣe àwọn sójà ló ṣe iṣẹ́ náà, wọ́n padà mú àwọn ọmọogun méje sùgbọ́n àwọn méjì ninú wọ́n ni wọ́n dásill pé wọ́n kò jẹ̀bi ẹ̀sùn kankan.
Cameroon Atrocity: Àwọn sójà náà ní ìyá àti àwọn ọmọ náà jẹ́ ikọ̀ Boko Haram
Ikọ ọmọ ogun orilẹ-ede Cameroon marun un ni yẹ ki wọn gba idajọ loni lẹyin ti iwadii ile ẹjọ fihan pe wọn jẹbi ẹsun iṣekupani ti wọn fi kan wọn.
Ṣugbọn Adajọ ti sun ọjọ idajọ rẹ di ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹsan an, ọdun 2020 yii.
Eyi tumọ si pe idajọ di oṣu to m bọ ko to waye lori awọn maraarun.
Aarọ Ọjọ Aje, Ọjọ Kọkandilọgbọn, Oṣu Kẹjọ, ọdun 2020 ni awọn soja naa de ileẹjọ awọn ọmọogun, lẹyin ti wọn rii wi pe wọn jẹbi ẹsun iwadii ti ''BBC Africa Eye'' ṣe ni ọdun 2018 ti wọn si pe ni "2018 Anatomy of a killing" .

Idajọ naa n waye lẹyin ọsẹ kan ti ileẹjọ dajọ pe awọn ọmọ ogun marun un ninu meje lo jẹbi ẹsun ipaniyan naa, nigba ti awọn meji gba ominira ni Ọjọ Kẹtadinlogun, Oṣu Kẹjọ, ọdun 2020.
Lẹyin ọdun kan ti iwadii fihan pe awọn soja naa pa iya ati ọmọ rẹ ni agbegbe Zelevet, ni Ariwa orilẹede Cameroon ni igbẹjọ naa bẹrẹ.
- Kayode Williams ọmọ lẹyin Oyenusi, ògbóǹtarìgì adigunjalè tó ń fi àyípadà rẹ̀ ran àwọn ẹlẹ́wọ̀n lọ́wọ́
- Ìjà d'ópin, fún ìgbà àkọ́kọ́, bàálù gbéra láti Israel lọ sí UAE
- Iléẹjọ gíga jùlọ da ẹjọ́ SDP àti PDP nù, wọ́n ní Yahaya Bello ló wọlé ìbò gómìnà Kogi
- Ìjọba Ghana ṣí iléeṣẹ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà padà. ó fún Nàìjíríà l'èsì àwọn ẹ̀sùn tó fi kàn-án
Agbẹjọro to ba BBC Yoruba sọrọ ni awọn soja meji ti wọn da silẹ naa, Godwe Mana Didier, Manasse Djakobei Johnathan ko kopa ninu iṣekupani naa, wọn kan tẹle awọn soja to yinbọn pa wọn ni.
Orukọ awọn marun un ti wọn jẹbi ẹsun ipaniyan naa ni Fabassou Etienne, Bitouala Ciriaque, Tchanga Chiengang Jean B, Donassou Gorvo Barnabas, Ntienche Feuroli Ghislain Landry.

Bawo ni awọn ikọ ọmọogun ilẹ Cameroon ṣe pa obinrin kan ati awọn ọmọ rẹ?
- Ọdun 2018 ni fidio kan ja ranyin kaakiri lori ẹrọ ayelujara nibi ti awọn soja ti ṣekupa obinrin ati awọn rẹ ti wọn pe ni ikọ agbesunmọmi Boko Haram, ti wọn si yinbọn pa wọn.
- Ni Oṣu Keje, ọdun 2018 ni ijọba orilẹede Cameroon sọ wi pe awọn soja naa kii ṣe ikọ ọmọogun wọn, ati wi pe orilẹede Mali ni iṣekupani naa ti waye.
- Ni Oṣu Kẹwa, ọdun 2018 ni ikọ BBC Africa Eye lo imọ ẹrọ ofintoto igbalode lati tọ pinpin bi ipaniyan naa ṣe waye, ati awọn to wa nidi ipaniyan naa, ti wọn si pe akọle rẹ ni "Anatomy of a killing'.
- Iwadii naa fihan iru ibọn ti awọn soja naa lo, ati aṣọ awọn soja naa, to fi mọ bata ẹsẹ wọn ati bi wọn ṣe rọ ibọn lu iya ati awọn ọmọ rẹ.
- Ẹsun ti wọn fi kan awọn eniyan naa ni ede Faranse ti wọn n sọ, ni wi pe awọn ikọ Boko Haram ni obinrin naa ati awọn ọmọ rẹ.
- Iwadii naa fihan pe ọdun 2015 ni ipaniyan naa waye.
- Ni Oṣu Kẹjọ, ọdun 2019 ni ijọba orilẹ-ede Cameroon fi lede wi pe awọn ti bẹrẹ igbẹjọ awọn soja meje ti wọn furasi wi pe awọn lo ṣiṣẹ ibi naa.
- Ni Oṣu Kejila, ọdun 2019 ni wọn gbe ẹjọ naa kuro ni ileẹjọ gbogboogbo lọ si ileẹjọ awọn ọmọ ogun, ti awọn araalu ko si lẹtọ si igbẹjọ naa mọ.
- Ni Oṣu Kẹjọ, ọdun 2020 ni ileẹjọ ologun da awọn meji silẹ ninu awọn meje naa wi pe wọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.
- Ni Ọjọ Kọkandilọgbọn, Oṣu Kẹjọ, ọdun 2020 ni ileẹjọ yoo da ẹjọ fun awọn soja marun un ti wọn jẹbi iṣekupani naa.



















