Rabiu Yusuf: Ọ̀gá ọlọ́pàá lẹ́kùn kẹrìnlá, Zone 14, AIG Rabiu Yusuf jáde láyé lẹ́yìn àìsàn ráńpẹ́

Rabiu Yusuf

Oríṣun àwòrán, others

Ọga ọlọpaa lẹkun apapọ kẹrinla ileeṣẹ ọlọpaa, (Zone 14) ni Katsina, AIG Rabiu Yusuf ti jade laye.

Iroyin nipa iku rẹ ko tii fi bẹẹ han sita, ṣugbọn awọn iwe iroyin abẹle kan lorilẹ-ede Naijiria n sọ pe owurọ ọjọ Abamẹta lo jade laye.

Ni aipẹ yii ni Rabiu Yusuf gba igbega si ipo ọga ọlọpaa AIG ti wọn si yan an gẹgẹ bi ọga agba ọlọpaa tuntun fun ẹkun kẹrinla ti ileeṣẹ ọlọpaa ṣẹṣẹ da silẹ ni ipinlẹ Katsina.

Ṣaaju ipo rẹ tuntun yii lo ti jẹ kọmiṣọnna ọlọpaa fun ipinlẹ Kano.

Àkọlé fídíò, Natalia Mufuta ìyá Yakub, Kamil àti Adam sọ̀rọ̀ lórí bí wọ́n ń sọ èdè mẹ́rin pàpọ

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Kano, Gambo Isah ṣalaye fun awọn ileeṣẹ iroyin abẹle kan pe, AIG Rabiu Yusuf jade laye "lẹyin aisan ranpẹ."

O gbadura pe ki Olorun forijin oku naa, ko si fi Aljana rọ ọ lọrun.

Koda, iroyin ni Rabiu ko tii bẹrẹ iṣẹ ni kikun ni ọọfiisi rẹ ni ipo tuntun AIG ẹkun tii ko to di oloogbe.

Àkọlé fídíò, Bí ẹ ṣe mọ̀wé tó, ẹ wá dánrawò níbí pẹ̀lú "Àpólà Ọ̀rọ̀ Orúkọ - Noun Phrase