Ondo accident: Tírélà méjì tẹ ìyá àti ọmọ pẹ̀lú èèyàn méjì míì pa ní Ikare-Akoko, awakọ̀ sá lọ

Ija

Oríṣun àwòrán, Other

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro sọ fun BBC Yoruba pe awọn eeyan to farapa nibi iṣẹlẹ naa si n gba itọju lọwọ nile iwosan.

ASP Ikoro ṣalaye pe awakọ kan wa ninu awọn eeyan mẹrin to gbẹmi mi ninu iṣẹlẹ naa, nigba ti awakọ keji sa lọ nitori ẹru ba a pe awọn eeyan le lu u pa.

Ọgbẹni Ikoro fikun ọrọ rẹ pe obinrin ati ọmọ rẹ naa wa lara awọn to ku ninu ijamba ọkọ naa.

O ni ileeṣẹ ọlọpaa si n wa awakọ to sa lọ lẹyin ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ tan

Adura nla ni Yoruba maa n gba pe Eleduwa ko ni jẹ ka rin arin fẹsẹ ṣi.

Ijamba ọkọ tirela meji ti ran eeyan mẹfa lọ si ọrun ọsan gan gan niluu Ikare-Akoko nipinlẹ Ondo.

Iṣẹlẹ ọhun waye lọjọ Abamẹta, ọgbọnjọ oṣu kẹjọ, ọdun 2020 nigba ti bireki ọkọ nla meji ọhun ja lori oke.

Ijamba ọkọ tirela meji

Oríṣun àwòrán, Other

Nibi tawọn awakọ ti n gbiyanju lati fi jia da awọn tirela naa duro ni ọkọ mejeeji ti lọ fẹnu sọ awọn ṣọọbu to wa lẹba ọna nibi ti eeyan mẹrin ti ṣagbako iku ojiji.

Lati ipinlẹ Ekiti lawọn ọkọ nla ti n bọ, ilu Akure ni wọn n lọ ki ijanu ọkọ wọn to ja ti ko si le mu un mọ.

Àkọlé fídíò, Bí ẹ ṣe mọ̀wé tó, ẹ wá dánrawò níbí pẹ̀lú "Àpólà Ọ̀rọ̀ Orúkọ - Noun Phrase