Ondo elections: Iroju Ogundeji ní gómìnà Akeredolu ló wà nídí ìgbésẹ̀ yíyọ igbákejì rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Sunshinetruth
Igbakeji olori ile aṣofin ipinlẹ Ondo, Họnọrebu Iroju Ogundeji ti ṣalaye pe Gomina Rotimi Akeredolu lo wa ni idi igbesẹ ati yọ igbakeji rẹ ki o to di wi pe iduroṣinṣin awọn aṣofin kan ni ile naa pa okuta si gaari igbesẹ ọhun.
Họnọrebu Iroju sọ ọrọ yii di mimọ ninu ifọrọwerọ rẹ kan pẹlu BBC News Yoruba lori idajọ ile ẹjọ giga kan nilu Akurẹ lori yiyọ ti ile naa yọ awọn aṣofin mẹta nipo laipẹ yii.
Iroju ni ipilẹ idojukọ wọn ko ṣẹyin bi "Gomina (Akeredolu) ṣe ni ki a wa lọ ti ọwọ bọ iwe ka yọ igbakeji oun" eleyi to ni awọn kọ si nitori awọn ri igbakeji gomina Agboọla Ajayi gẹgẹ bii " alaiṣẹ"
- Oral Sex: Bóo bá ń gba ẹnu ní ìbálòpọ̀, wo àìsàn tóo lè kó lójú ara rẹ
- Ìdí tí mo fi gbàdúrà ìyàwó bíi Chanel Chin fáwọn tó d'ẹ̀bi ìkọ̀sílẹ̀ rẹ̀ rù mí rèé - Oluwo
- Ẹlikọ́pítà Quarom aviation já lulẹ̀ ní Ikeja, gbogbo èrò inú rẹ̀ ló ti tẹ́rí gbaṣọ!
- Kìí ṣe torí ìbèérè ni mo ṣe bẹ́ Fani-Kayode, àwọn akẹẹgbẹ́ mi ló kó mi láyà jẹ - Eyo Charles
Ṣe o ṣeeṣe ki gomina ati igbakeji rẹ wa lori aleefa ki awọn aṣofin o gbero lati yọ igbakeji gomina kuro nipo lai jẹ pe gomina mọ sii? Ododo ibẹ ni pe gomina ni ko fẹ igbakeji rẹ mọ to si ke gbajare si awọn aṣofin pe awọn ni agbara wa lọwọ wọn ki wọn ba oun yọ ọ"
Igbakeji olori ile aṣofin naa tun fi kun un pe idi ti awọn fi faake kọri pe awọn ko ni fọwọ si yiys igbakeji gomina nipo ni pe, gomina Akeredolu ko ri ti awọn ro gẹgẹ bi aṣofin, ọdọ igbakeji gomina yii ni awọn aṣofin ti n ri iranlọwọ ti ile naa nilo gba.
Ki ni ile ẹjọ sọ?
Orisunmibare lorukọ tawọn aṣofin mẹta ti wọn fofin lọ rọkun nile de nile aṣofin ipinlẹ Ondo naa yoo maa jẹ bayii pẹlu bii ile ẹjọ ṣe ni ki wọn san miliọnu marundinlogun naira fun wọn.
Ile ẹjọ giga kan ni ilu Akurẹ lo gbe idajọ kalẹ pe ki igbakeji olori ile naa, Ogundeji Iroju, aṣofin Favour Tomomowo ati Wale Williams o pada si ijoko wọn ni ile ki wọn gba owo gba mabinu lọwọ
Awọn mẹta yii wa lara awọn aṣofin mẹjọ to kuna lati tọwọ bọ iwe ati dibo yọ igbakeji gomina ipinlẹ naa, Họnọrebu Agboọla Ajayi.
Lẹyin to ni ki wọn san owo gba maa binu naa fun awọn aṣofin yii, ile ẹjọ tun ni ki wọn da wọn pada sori ijoko wọn ni ile naa.
Adajọ naa to gbẹjọ naa, Onidajọ Ademọla Bọla ṣakawe yiyọ ti wọn yọ awọn aṣofin naa nipo bi eyi ti ko ba ofin mu ti ko si ribi duro si labẹ iwe ofin orilẹede Naijiria.













