Ghana Vs Nigeria trade war: Eyín àti ahọ́n a máa bá ara wọn jà, ọ̀kan ṣoṣo ni Nàìjíríà àti Ghana

Oríṣun àwòrán, Speaker media department
Agbẹnusọ ile igbimọ aṣojuṣofin Naijiria, Femi Gbajabiamila ti ṣe ipade pẹlu akẹgbẹ rẹ nilẹ Ghana lọna ati petu saawọ to n waye laarin orile-ede mejeeji.
Irinajo Gbajabiamila jẹ ọkan lara ọna ati lọ wa ojutuu si ọrọ owo miliọnu kan dọla ti orilẹ-ede Ghana ni ki awọn ọmọ Naijiria to n taja lọhun maa san.
Gbajamiala to kọwọrin pẹlu awọn aṣofin ilẹ Naijiria la gbọ pe adari ile aṣojuṣofin ilẹ Ghana, Mike Oquaye gba lalejo.
- Aṣẹ́wó, olè, gbájúẹ̀ ni 723 ọmọ Naijiria ta lé padà sílé - Ghana
- Òtítọ́ ọ̀rọ̀ rè é lórí ilẹ̀ tó fa awuyewuye láàrin Ghana àti Nàìjíríà
- Wọn le awọn olutaja kuro niwaju ile Aarẹ Ghana
- Ìjọba Ghana ṣí iléeṣẹ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà padà. Ó fún Nàìjíríà l'èsì àwọn ẹ̀sùn tó fi kàn-án
- Ará ìlú figbe ta bí wọ́n ṣe ní jálá epo bẹntiróò ṣe tún lọ sókè di ₦151.56k
Ninu ọrọ rẹ, Gbajabiamila sọ pe eyin ati ahon a maa ba ara wọn ja nitori naa ede aaiyedeto n waye laarin Naijiria ati Ghana ko yẹ ko fa wahala.
O ni ohun to ṣe pataki ni i awọn orileede mejeeji wa ọna labẹ ofin ti wọn yoo fi yanju aawọ to ba waye.
Lọsẹ to kọja ni awọn ọmọ Naijiria figbe ta pe awọn ko lee gba bi orilẹede Ghana ṣe n wọ awọn nilẹ ti wọn si n foju keree wọn.
Ṣugbọn awọn alaṣẹ Ghana ni bẹẹ kọ ni ọrọ ṣe ri nigba ti ijọba Naijiria naa fọrọ ikilọ ranṣẹ pe ki wọn ṣọra gidi gan.
Adari ile Ghana ninu esi rẹ sọ pe oun ni igbagbọ pe laarin ọjọ kan si meji awọn yoo yanju ọrọ naa.
O ni nilẹ Afrika eeyan ko le darukọ Naijiria ko ma pe Ghana pẹlu rẹ.

Oríṣun àwòrán, Speaker media department
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Kogi kéde ọjọ́ ìwọlé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ padà sí iléèwé
- Ará ìlú figbe ta bí wọ́n ṣe ní jálá epo bẹntiróò ṣe tún lọ sókè di ₦151.56k
- Ọkọ̀ tírélà 3 kọlu ọkọ̀ ìgboro, obìrin 2 kú, 6 farapa yánnayànna
- Iléeṣẹ́ ìròyìn Daily Trust gbọdọ̀ san N6 bilion nítorí ìbanilórúkọjẹ́- Femi Fani Kayode
- Kí ló wá nínú àbádòfin pínpín omi àti àwọn ǹkan inú omi tó ń mú awuyewuye wa?

Oríṣun àwòrán, others
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Ìjọba Ghana ṣí iléeṣẹ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà padà. Ó fún Nàìjíríà l'èsì àwọn ẹ̀sùn tó fi kàn-án
Ijọba Ghana wí àwíjàre rẹ̀ lórí àwọn ẹ̀sùn tí Nàìjíríà fi kàn-án
Ijọba orilẹ-ede Ghana ti fesi si ẹsun ti ijọba Naijiria fi kan, pe wọn n fi iya jẹ awọn ọmọ Naijiria nibẹ.
Minisita fun eto iroyin ni orilẹ-ede Ghana, Kojo Oppong Nkrumah sọ pe Aarẹ Nana Akufo-Addo yoo jiroro pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari, lati yanju ọrọ naa ni tubi-inubi.
O tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe Ghana nifẹ si ibasepọ to wa laarin orilẹ-ede mejeeji.
Opin ọsẹ to kọja ni Minisita eto iroyin ni Naijiria, Lai Mohammed kilọ fun Ghana pe 'o to gẹ'.
Eyi waye lẹyin ti Ghana ti awọn ile itaja keekeeke to jẹ ti awọn ọmọ Naijiria pa.
- Wo nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Tolanibaj, Wathoni àti Brighto ni wọ́n lé kúrò ni BBNaija l'ọ́sẹ̀ yìí
- "Mi ò ní wọ Uber mọ́ tí wọ́n bá leè fi owó lée nítorí àfikún owó orí tí Sanwo Olu ṣe"
- Àwọn nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa ṣíṣe ìṣirò àsìkò tí o bá n yé ẹyin
- Èèyàn méjì kú, méjìdínlógóje míì ṣẹ̀ṣẹ̀ kó COVID-19 lọ́jọ́ Àìkú
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko kéde ọjọ́ tí àwọn iléèwé gígá yóò wọlé
Ijọba Naijiria sọ pe ohun ti ni akọsilẹ gbogbo iwa buruku tí awọn alasẹ Ghana n hu si awọn ọmọ Naijiria to n gbe l'orilẹ-ede wọn.
Sugbọn Ọgbẹni Nkrumah sọ pe gbogbo nkan ti Lai Mohammed tọka si kii ṣe otitọ.
Atejade naa ni: "Nitori naa, gbogbo iwọde, igbesẹ tabi iwa ti Naijiria ba hu nitori awọn iroyin to gbọ, ko bojumu."
Nkrumah tẹsiwaju pe ọrọ ti Lai sọ nipa ibasepọ Naijiria pẹlu Ghana lo kọ awọn lomiinu julọ.

Oríṣun àwòrán, others

Oríṣun àwòrán, others

Oríṣun àwòrán, others

Oríṣun àwòrán, others

Oríṣun àwòrán, others

Oríṣun àwòrán, others
Lori ẹsun ti Naijiria fi kan Ghana pe o gba ileesẹ aṣoju oun, Nkrumah sọ pe, ọdun mẹrindinlaadọta sẹyin ni adehun ti orilẹ-ede mejeeji fọwọ́ si pẹlu ẹni to ni ile naa, Thomas D. Hardy, ti dopin, sugbọn ti Naijiria ko ṣe i mi.
Yatọ si eyi, Ọgbẹni Nkrumah sọ pe irọ ni pe awọn fi ọmọ Naijiria bi i 700 sì ẹ̀wọ̀n lai nidi. O ni, gbogbo wọn lo jẹbi ẹsun iwa ọdaran ni ijọba ṣe mu wọn.
- Wọ́n tún ti pa omidan ẹni ọdún 18 míràn l'Akinyele ní ìlú Ibadan
- Irọ́ ni, kò sí olóyún nínú àwọn tí Tírélà pa ní Ondo ṣùgbọ́n awakọ̀ ti sá lọ- Ọlọ́pàá Ondo
- Ta ni ìyàwó Chadwick Boseman, tó jẹ́ àwòkọ́ṣe rere f'áwọn ọ̀dọ́ Adúláwọ̀?
- Rabiu Yusuf, ìgbákejì ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá Nàìjíríà (AIG) lẹ́kùn Katsina jáde láyé
Lori pe ijọba Ghana ti awọn ile itaja to jẹ ti awọn ọmọ Naijiria, Nkrumah sọ pe awọn onitọhun ko tẹle ilana ti ijọba fun wọn, ni ọrọ ṣe ri bẹ ẹ.
Sugbọn ṣa, o ni ijọba ti ṣi wọn pada.



















