Bolt in Lagos: Àwọn iléeṣẹ́ Uber yóò kógbánílẹ̀ tí ìjọba Eko bá fi lé owó orí wọn- Onimọ̀ nípa ọrọ̀ ajé

Taxi sign and Uber app

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn olugbe ipinlẹ Eko kan to maa n wọ ọkọ Uber ati Bolt ti sọ pe kii ṣe asiko yii lo yẹ ki ijọba ipinlẹ naa gbe owo ori gọbọi le awọn ileeṣẹ naa lori.

Lara awọn eeyan naa to ba BBC sọrọ ti ko fẹ ki a darukọ oun sọ pe, kii ṣe ohun to mu ọgbọn wa ni ijọba fẹ ṣe nitori alekun owo ori naa yoo tumọ si afikun owo ọkọ Uber tabi Bolt ọhun.

O ni "ti wọn ba gbe owo le owo ọkọ wọn lori, awọn eeyan ko ni ba awọn ileeṣẹ naa duna dura mọ, to n tumọ si pe awọn awakọ awọn ileeṣẹ naa yoo padanu iṣẹ wọn.

Ẹlomiran to tun ba BBC sọrọ, Lolade Odujoko sọ pe ti wọn ba lee ṣafikun owo ọkọ aladani Uber, o n tumọ si oun ko ba wọn dowopọ niyẹn.

Lolade ni "Kaka ki n san owo gobọi fun Uber tabi Bold, niṣe ni mo maa lọ wọ ọkọ Danfo tabi Molue nitori ko si owo lasiko yii."

Lẹyin naa lo ni iba dara ki ijọba ipinlẹ Eko tun ero rẹ pa lori igbesẹ ọhun.

Kini o ṣeeṣe lati ṣẹlẹ?

Ẹwẹ, onimọ nipa eto iṣuna kan, Olumide Ibikunle nigba to n da si ọrọ naa sọ fun BBC pe, ohun to fa ọrọ naa ni pe awọn ileeṣẹ naa ko gba awọn awakọ rẹ gẹgẹ bi oṣiṣẹ, nitori naa ko lee gba owo ori lori wọn.

O ni eredi ree ti ijọba Eko ṣe gbe ọna abayọ owo tuntun naa kalẹ lati lee ri owo to yẹ gba lọwọ awọn ileeṣẹ ọhun.

O fi kun pe awọn ileeṣẹ naa ati ijọba ni lati jokoo fun ijiroro lori ọna abayọ, bi bẹẹ kọ, o ṣeeṣe ki awọn ileeṣẹ ọhun fi ipinlẹ Eko silẹ lọ awọn ipinlẹ miran, tabi ki wọn tilẹ orilẹ-ede Naijiria sile gan paapaa.

Ṣaaju ni ijọba ipinlẹ Eko ti kede pe awọn ileeṣẹ ọkọ aladani bii Uber ati Bold yoo maa san ida mẹwaa owo ti wọn ba n gba lọwọ awọn onibara wọn.

Bẹẹ lo tun ni ki awọn ile iṣẹ naa maa san miliọnu marundinlọgbọn naira lọdọọdun fun awọn gẹgẹ bi owo ori lori ọkọ ẹgbẹrun un kan ati ọkan to ba wa nikawọ rẹ.

Àkọlé fídíò, Alaafin: Olori Aanu Adeyemi ṣàlàyé ìdí tó ṣe gẹ́ Oba Lamidi Adeyemi ti ìlú Oyo

Awọn oṣiṣẹ Uber ati Bolt to n wa ọkọ naa ti a ba sọrọ ṣugbọn ti wọn ko fẹ ki BBC darukọ awọn ṣalaye pe nkan ko rọgbọ lasiko ajakalẹ arun coronavirus yii nitori ọpọ eeyan ko jade, awọn miran ti padanu iṣẹ wọn.

Ati pe ko si owo ni igboro ni eyi to maa mu ki igbese ijọba ipinlẹ Eko yii tubọ nira sii fun tẹrutọmọ.

Wọn rawọ ẹbẹ si ijọba ipinlẹ Eko pe ki wọn dakun ma gbe iru igbesẹ afikun owo ori nla yii niru asiko ti gbogbo eto ọrọ aje dẹnukọle ni agbaye yii.

Gbogbo akitiyan BBC Yoruba lati kan si Uber tabi Bolt lo ja si pabo.