Nigerian high commission in Ghana: Ọ̀rọ̀ n yanjú bọ̀, ìjọba Ghana ni yóò kọ́ ilé tí àwọn kan wó

Ileeṣẹ aṣoju Naijiria ni Ghana

Oríṣun àwòrán, Dele Momodu/fred smith

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ijọba orilẹ-ede Ghana sọ pe iwadii awọn ṣafihan lootọ ni ilẹ ti wọn kọ ileeṣẹ aṣoju Naijiria ni Ghana si ni awuyewuye lori.

Wọn ni ilẹ naa wa lara awọn ilẹ to wa labẹ akoso idile ọmọọba Osu ni agbegbe naa.

Ileesẹ ijọba Naijiria ni Ghana ni iwe ẹri to ni nọmba idanimọ SCR/LCS 74/VOL.2/95 ti wọn buwọlu lọjọ Keje osu Kẹjọ ọdun 2000.

Iwe yi fun wọn lẹtọ si ilẹ eeka mẹrin to wa ladugbo Osu Mantse Layout.

Ileesẹ ijọba Naijiria sọ pe oun ni gbogbo iwe ẹri pe wọn san owo to yẹ fun akọwe agba ileesẹ to n dari ọrọ ilẹ ni Ghana.

Ṣugbọn, ileesẹ naa ko fun wọn ni iwe ẹri to yẹ lori ilẹ naa.

Ileesẹ ijọba Ghana to n dari ọrọ ilẹ ni awọn ko ni akọsilẹ to fi han pe ileesẹ ijọba Naijiria san owo kankan lori ilẹ naa.

Nigba ti awọn idile ọmọọba Osu wa kọwe pe awọn fẹ gba iyọnda lati ta ilẹ naa f'ẹlomiran, ileesẹ to n dari ọrọ ilẹ lawọn kọwe si ileesẹ orileede Naijiria ni Ghana lati pese iwe ẹri ti wọn ni ṣugbọn awọn ko gbọ nkankan lati ọdọ wọn.

Wọn ni nigba ti wọn ko da awọn lohun lo mu ki awọn fun ẹlomiran to fẹ ra ilẹ naa ni iwe aṣẹ lori ilẹ yi kanna.

Ileesẹ to n dari ọrọ ilẹ sọ pe oun wadii orukọ wọn ninu akọsilẹ awọn to ni iwe ẹri, awọn ko ri aridaju pe wọn tẹle ilana to yẹ lati fi ra ilẹ naa.

Labẹ ofin Vienna to de ibaṣepọ laarin awọn orileede, eeyan ko le fọwọ kan ilẹ orileẹde kan nibi to ba wa nilẹ mii.

Ileesẹ okeere orile-ẹde Naijiria ati awọn ọfisi to rọ mọ wa labẹ aabo ofin yi.

Nitori idi eyi, ko tọ bi wọn ti ṣe wo apa kan ileesẹ ijọba Naijiria ni Ghana lọjọ kọkandinlogun oṣu Kẹfa.

Ipinnu ijọba Ghana ree

Ileesẹ to n dari ọrọ ilẹ yoo fun ileesẹ ijọba Naijiria ni iwe ẹri to peye.

Eyi yoo fi han pe idile ọmọọba Osu gba owo pe awọn ta ilẹ fun ileesẹ ijọba Naijiria l'oṣu Kẹjọ, ọdun 2000.

Ileesẹ ijọba Ghana to n dari ọrọ ilẹ yoo wa fun wọn ni ẹkunrẹrẹ iwe aṣẹ lori ilẹ naa.

Ijọba Ghana yoo ṣe ijiroro pẹlu idile ọmọọba Osu to ta ilẹ naa lati yanju ọrọ to wa nilẹ yi.

Minisita fun ọrọ ilẹ okere ni Ghana ti sọ pe orilẹ-ede naa ni yoo kọ apa kan ọfisi ileesẹ orileede Naijiria ni Ghana t'awọn kan wo lulẹ ni Accra.

Wọn yoo gbe igbesẹ to yẹ nipa iwadii awọn ti ọlọpaa mu pe wọn lọwọ si wiwo apa kan ileesẹ orileẹde Naijiria ni Ghana.

Ṣaaju ni Aarẹ orilẹ-ede Ghana, Nana Akufo-Addo tọrọ aforiji lọwọ orilẹ-ede Naijiriai lori bi wọn ṣe wo ile naa.

Oluranlọwọ Agba fun Aarẹ Muhammadu Buhari, Garba Shehu lo fi iroyin naa sita.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ọjọ Iṣẹgun ni Akufo-Addo ba Aarẹ Muhammadu Buhari sọrọ lori ẹrọ ibanisọrọ, to si sọ pe tinu-tinu ni oun fi rawọ ẹbẹ fun bi awọn ọmọ orilẹ-ede oun kan ṣe wo ileeṣẹ aṣoju Naijiria ni Ghana.

Bakan naa lo sọ fun Aarẹ Buhari pe, oun ti paṣẹ pe ki iwadii to muna doko ko bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.

Ṣaaju ki Akufo-Addo to o pe Aarẹ Buhari, ọwọ tẹ awọn afurasi kan, wọn yoo si gbe wọn lọ si ile ẹjọ.

Ninu ọrọ to tun ba BBC sọ, Shehu sọ pe iroyin to tẹ awọn lọwọ ni pe "olóyè kan ni agbegbe naa lo ṣagbatẹru bi wọn ṣe wo ile naa."

Ṣugbọn o ni iwadii nikan ni yoo tu aṣiri nkan to ṣẹlẹ ni pato, awọn to hu iwa naa, ati idi ti wọn fi hu u.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Lori iroyin kan to n lọ pe awọn to wo ile naa sọ pe ilẹ ti Naijiria kọ ọfiisi naa si kii ṣe ti ẹ, Garba Sheu sọ pe ko ṣe e ṣe ki orilẹ-ede kan deede kọ ile si orilẹ-ede miran, lai gba aṣẹ lọwọ ijọba ibẹ.

Garba Shehu tun sọ pe gbogbo ariwo awọn ọmọ Naijiria lori iṣẹlẹ naa ni awọn ti gbọ.

"Ko ṣe e ṣe ki Naijiria o jà ni Ghana, bi awọn kan ṣe n beere fun. Awọn olori ni yoo yanju ọrọ naa lọna to tọ, lai da wahala tabi ọta silẹ laarin awọn eniyan orilẹ-ede mejeeji."

Ọjọ Aje ni ijọba Naijiria ranṣẹ pe igbakeji aṣoju orilẹ-ede Ghana, Arabinrin Iva Denoo, lori bi awọn kan ṣe wó abala kan ni ileeṣẹ aṣoju Naijiria ni Ghana.

Minisita fun ọrọ ilẹ okeere, Geoffrey Onyeama sọ ninu ikede kan lọjọ Aje pe "mo ranṣẹ pe Arabinrin Iva Denoo, pe ko wa ṣalaye ni kiakia lori ikọlu to waye laipẹ yii si ọ̀kan lara awọn ile to wa ni inu ọgba ileeṣẹ aṣoju Naijiria".

Aṣoju Ghana ati Geoffrey Onyeama

Oríṣun àwòrán, @GeoffreyOnyeama/twitter

Ọjọ Ẹti ni awọn gende agbebọn ni Ghana yabo ile'gbe aṣoju orilẹ-ede Naijiria ni Ghana, ti wọn si fi kata-kata wó awọn ile kan ninu ọgba naa.

Ile ti wọn wo naa jẹ eyi ti wọn n kọ lọwọ fun awọn oṣiṣẹ rẹ, ati awọn aṣoju ilẹ okeere to ba wa si ọfiisi naa.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ redio kan nilu Accra , Joy FM, sọ pe ọkunrin kan to ko nkan ija dani, dunkooko mọ awọn oṣiṣẹ ọfiisi naa to wa nibi ti wọn ti n wo ile naa pe "oun yoo palẹ wọn mọ ti wọn ba sun mọ oun".

Olori awọn oṣiṣẹ alaabo ni ileeṣẹ aṣoju Naijiria nibẹ, Emmanuel Kabutey sọ fun Joy FM pe, ọkunrin naa sọ pe awọn ni atilẹyin ileeṣẹ alaabo Ghana, nitori naa ẹni to ba sun mọ awọn yoo fara gba ọta.

Ọgbẹni Kabutey sọ pe "awọn ọlọpaa to wa sibi iṣẹlẹ naa ko sọ ohunkohun, wọn kọ lọ si ibi ti ọkunrin to lewaju awọn agbebọn naa duro si, wọn ba sọrọ ọrẹ si ọrẹ, wọn gba nọmba ara wọn, wọn si yọnda rẹ ko ma a lọ".

Àkọlé fídíò, Asa Trokosi nibi ti ọmọde ti n jiyan ẹsẹ mọlẹbi rẹ , wọpọ ni Ghana, Togo ati Benin.

Iṣẹlẹ naa to waye lọjọ Ẹti to kọja fa awuyewuye laarin awọn ọmọ Naijria, koda Minisita fun ọrọ ilẹ okeere ni Naijiria, Geoffrey Onyeama ti sọ pe ijọba Naijiria koro oju si iṣẹlẹ naa.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Ninu atẹjade kan to fi sita lori Twitter lọjọ Aiku, Onyeama sọ pe "awọn n beere fun igbesẹ kiakia lati ọdọ ijọba orilẹ-ede Ghana, lati wa awọn to ṣe ikọlu naa sita, ki wọn o si tun pese aabo fun dukia ati ẹmi awọn ọmọ Naijiria to wa ni Ghana.

Àkọlé fídíò, Ọmọ Nàìjíríà fárígá lórí olú iléeṣẹ́ Nàìjíríà tí wọ́n wó ní Ghana

Iṣẹlẹ naa mu ki awọn ọmọ Naijiria kan to n gbe ni Ghana o ṣe iwọde lati tako iṣẹlẹ naa, ti awọn kan lara wọn to ba akọroyin BBC, Favour Nuno, sọrọ pe ijọba Ghana ti ti ile itaja wọn pa lati bi oṣu mẹjọ, ti wọn kii ṣi tun fi oju're wo awọn ọmọ Naijiria nibẹ.

Iroyin sọ pe arakurin oniṣowo kan lo sọ pe ori ilẹ oun ni wọn kọ ileeṣẹ Naijiria yii si ni Ghana. O yọju lọsẹ to kọja pẹlu awọn ẹri kan lati fi ti ọrọ rẹ lẹyin, ko to o di pe o bẹrẹ si ni wo odi ti wọn mọ yi ile naa ka lulẹ.