Yoruba Films: Adewale Elesho ní àìkàwé ló ṣàkóbá fún òun nínú iṣẹ́ tíátà

Adewale ati Yemi Elesho

Oríṣun àwòrán, Instagram/officialyemielesho

Gudugbẹ ja ninu ifọrọwẹro BBC Yoruba pẹlu gbajumọ oṣere tiata, Adewale Adeoye Elesho ati ọmọ rẹ, Yemi Elesho.

Adewale Elesho ni oju ti ri to ninu irin ajo oun lati ilẹ, o ni oun kewu lẹyin ti oun pari iwe alakọbẹrẹ tan.

Elesho, gẹgẹ bi ọpọ ṣe maa n pe e ninu ere sọ pe, oun pada kọ iṣẹ oogun tita, ti oun si gba iyọnda lọdun 1975, bakan naa loun ṣi ṣọọbu oogun toun ni 1976.

Adewale Elesho ni baba oun fun oun lowo bẹẹdi ati foomu nigba ti oun bẹrẹ si ni ta oogun, tori baba oun ni ko yẹ ki ẹni ti o n ta oogun maa sun sori ẹni.

"Awọn ọlọpaa maa n yọ mi lẹnu nibi iṣẹ oogun tita ni ilu Emure ti mo n gbe nipinlẹ Ondo nigba naa, eyi gan an lo jẹ ki n fi iṣẹ oogun tita silẹ, ti mo fi bẹrẹ ere tiata ṣiṣe."

O ni oun ati ọrẹ oun jọ dawo ra danfo ti wọn fi bẹrẹ ere tiata, laye igba naa lọhun.

''Baba mi ko fẹ ki n ṣiṣẹ tiata, o ni iṣẹ tiatia yoo jẹ ki n maa ṣe oogun,'' Elesho lo woye bẹẹ.

Nigba to ya ni Elesho pada de ọdọ oloogbe Adeyemi Afolayan, ti ọpọ mọ si Ade Love.

O sọ pe awọn olootu ere tiata laye igba naa maa n kọ ẹnu ifẹ si awọn arẹwa obinrin laarin awọn oṣere.

Elesho sọ pe nipasẹ Ade Love loun fi mọ Oga Bello, Isho Pepper ati Iya Awero ninu ere ṣiṣe.

Adewale ati Yemi Elesho

Oríṣun àwòrán, Instagram/officialyemielesho

Adewale Elesho ni aikawe oun ṣakoba fun oun ninu ṣugbọn oun dupẹ lọwọ Eleduwa.

O ni kewu ti toun ka ko ta ninu iṣẹ tiata.

Nipa awọn ọmọ rẹ, o ni ihoho ọmọluabi loun maa n ba awọn ọmọ oun wi, o ni gende ọkunrin marun un loun bi.

Elesho ni ''ọmọ obinrin mi nikan ni mi o ja si ihoho ri.''

O ni Bibeli sọ pe paṣan lo tu were to wa laya ọmọde kuro, ṣugbọn o ni ẹgba tẹẹrẹ ko ran awọn ọmọkunrin mọ, igbaju igbamu lo yẹ wọn.

Yemi Omo Elesho

Yemi Elesho to jẹ ọmọ Adewale Elesho ni tiẹ sọ pe, lati kekere loun ti bẹrẹ ere tiata, ''mama mi lo maa n gbe mi kaakiri ori itage.''

''Ati kekere ni mo maa ti n pa awọn agbalagba lẹrin, iwe kẹrin ni girama ni mo ti ko ẹgbẹ osere jọ.''

Wale Elesho

Oríṣun àwòrán, Instagram/officialwaleelesho

"Fiimu meji ti mo ṣe pẹlu awọn akẹgbẹ mi, ko si ẹni to gba lọwọ wa, nigba to ya ni gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ oṣere mi tuka, ti o si ku emi nikan."

Yemi sọ pe lẹyin naa loun bẹrẹ si wa Maruwa nitori oun ti sa kuro nile.

''Mo ti wa Maruwa lẹyin baba mi ri ṣugbọn wọn o mọ pe emi ni.''

''Ọjọ ti baba mi ri mi nibi ti mo ti n wa Maruwa, ni mo fii silẹ ti mo si pada sile.''

O ni lẹyin naa loun ṣẹṣẹ lọ si ile iwe eyi ti baba oun fẹ, ki oun tiẹ to le ṣe ohun kohun.