Jerusalema Remix: Wo orin l'édè Yoruba àti Zulu tí Burna Boy fi fa ayélujára ya

Jerusalema

Oríṣun àwòrán, @MasterKGsa

Gbajugbaja olorin ọmọ Naijiria, Burna Boy wa lara awọn orukọ to n falẹ ya loju opo Twitter latari awo orin tuntun, Jerusalema eyi to pawọpọ ṣe pẹlu ọmọ orilẹede South Africa kan, Master KG.

Ojo ti n pa igun kikọrin pọ awọn olorin ọmọ Naijiria ati South Africa bọ, ọjọ ti pẹ.

Bi o tilẹ jẹ pe ọtọọtọ ni ipilẹ orin kikọ lawọn ilu mejeji yii to si jẹ pe iṣọwọ kọrin wọn yatọ ṣugbọn awọn olorin gangan ti wa ọna ti ajọṣepọ wọn fi n ṣiṣẹ to ti n pọ owo gidi.

Ninu ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria to ti jọ kọrin pẹlu ọmọ South Africa ti a gbe yẹwo nisalẹ yii ati akọle orin wọn, a fi awo tuntun Burna Boy ati Master KG ṣe akọkọ ti wọn fi ede Yoruba ati Zulu kọrin ninu rẹ.

1. Jerusalema Remix - Burna Boy ati Master KG.

Atunkọ gangan ni orin ọmọ South Africa, Master KG yii jẹ leyi to ti kọkọ kọ, Jerusalema. Nigba ti yoo wa tun un gbe jade lo pe ọmọ tia Burna Boy si i, lorin ba di gbua lori ayelujara to n ta wara wara.

Burna Boy to ti gba oriṣiriṣi mi ẹyẹ fi ọna ilu Afro beat wọle to si dapọ m olohun gooro Nomcebo Zikode ninu orin naa.

Pabanbari rẹ ni pe ninu orin yii, Burna Boy fi ede Zulu lati South Africa ati ede Yoruba Naijiria kọrin ninu awo orin naa pẹlu Nomcebo Zikode.

2. Tchelete - (Davido ati Mafikizolo) (2014)

Olorin

Oríṣun àwòrán, @TheReUpShow

Orin Tchelete jẹ orin ayẹyẹ to si kun fun agbara. Ni kete tawọn olorin South Africa pe olorin pataki ọmọ Naijiria to jẹ ọlọwọ aje si i, ṣe lo gbe ẹwa orin naa jade to si wa di orin gbogbo igba lẹnu awọn eeyan - awọn ede to jẹyọ ninu orin ọhun ni ede Yoruba, Gẹẹsi, Pidgin ti Naijiria, Isizulu ati Isixhosa.

3. Soweto Baby - DJ Maphoriza pẹlu Wizkid ati DJ Bucks (2015)

Yoruba maa n ni "ati ranmu gangan ko sẹyin eekana. Aṣeyọri orin yii jẹ apapọ iṣẹ iyi ti olorin Naijiria, Wizkid ni lọja orin. Bakan naa ni DJ Buckz sa awọn ohun elo ibilẹ si i ninu to fi fakọyọ.

Àkọlé fídíò, Ó dára kí obìnrin níṣẹ́ lọ́wọ́ - Toyin Lawani

4. All For Love - Wizkid ati Bucie (2017)

Ninu awo orin yii, Wizki ọba orin Afro tun gbe tuntun yọ pe oun to gbangbaa sun lọyẹ pẹlu ọmọbabinrin nile orin eyi ti wọn fi jọ gbe orin "All For Love" jade pẹlu ede Yoruba, Xhosa ati Gẹẹsi ti Maphorisa tun wa sa awọn ohun elo orin bii duru, gita ati woroworo xylophone si i.

Olorin

Oríṣun àwòrán, @KayaFMMusic

6. Mountain- Waje ati Lira

Waje ni ọmọ Naijiria, Lira wa lati South Africa. Gbogbo agbara ọrun to wa ninu ohun Waje lo lo sinu orin yii. Pẹlu awọn ilu, fere ati ohun to rinlẹ ni Lira ati Waje fi ṣe awo orin ti kii ṣe dandan ko sọ oke iṣoro di ipẹtẹlẹ ṣugbọn fi igbagbọ si ni lọkan pe pẹlu ọkan alafia, oke iṣoro le di ipẹtẹlẹ.

6. Spirit - Kwesta ati Wale

Orin yii da lori ibọwọ fun ohun ti ẹmi. Olorin Naijiria, Wale lo gbogbo agbara ọkunrin to ni lati kọ ọrọ inu naa pe "mo le jẹ akewi fun ọ nile rẹ, mo le ba ọ ṣiṣẹ ọpa omi ẹrọ rẹ to ba bẹ...". O ṣe orin yii bi ẹni n pe ọgọọrọ awọn irumọlẹ Yoruba jade ni.