Tinubu sọ̀kò òrò sí Obaseki lẹ́yìn tó yọ òrùlé ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Edo

Tunubu

Oríṣun àwòrán, @AsiwajuTinubu

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Adari gbogboogbo fun ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu ti sọko ọrọ si gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki lẹyin to paṣẹ ki wọn yọ orule Ile Igbimọ Aṣofin ipinlẹ naa.

Tinubu lo sọ ọrọ naa loju opo Twitter rẹ, nibi to ti sọ pe iwa ti gomina ọhun wu jẹ idoju ija kọ ofin ati ijọba tiwantiwa.

Gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ naa bu ẹnu atẹ lu Obaseki , o si fẹsun kan an pe o n fi ofin Naijiria ṣe ẹlẹya ni bo ṣe dena iburawọle fun ida meji ninu mẹta awọn ọmọ ile ọhun ti wọn dibo yan.

Tinubu

Oríṣun àwòrán, @BOBCyril2

Gẹgẹ bi Tinubu ṣe sọ, Obaseki bẹ awọn janduku lọwẹ lati ba apakan ile igbimọ aṣofin naa jẹ, to si parọ pe ṣe ni oun fẹ ṣatunṣe rẹ.

O ni "Lẹyin naa lo ko yanri sẹnu ọna ile ọhun lati le dina mọ awọn to ba fẹ wọle sibẹ."

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Tinubu fẹsun kan Obaseki pe o na owo ilu lati fi ba ilu jẹ kaka ko fi tun ilu naa ṣe.

O ṣalaye siwaju si pe iwa Baṣọrun Gaa ni gomina ọhun wu ati pe o ti ja ireti awọn eeyan to n ṣejọba le lori kulẹ.

Tinubu sọ pe iwa ti Obaseki wu sẹyin to ki awọn aṣofin naa yọ nipo ṣugbọn wọn ko ṣe bẹẹ nitori wọn yan ọna alaafia.

Eekan ninu ẹgbẹ APC ọhun pari ọrọ rẹ pe ijọba gomina ọhun yoo wa sopin laipẹ ọjọ.

Àkọlé fídíò, Ìdílé tí ọkọ da ọmọ síta tóríi ojú Búlùú tí wọ́n ní bá BBC sọ̀rọ̀

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Obaseki: Ilé ẹjọ́ gíga àpapọ̀ fa ìwé ẹjọ́ tí wọ́n pè tako ìdíje Obaseki lẹ́gbẹ́ PDP

Aworan obaseki

Oríṣun àwòrán, other

Ile ẹjọ giga apapọ ilẹẹwa to wa ni ilu Portharcourt ti fa iwe ẹjọ ti wọn pe tako iduro gomina Godwin Obaseki gẹgẹ bi oludije ni idibo abẹle fun ipo gomina lẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Edo.

Ni ọjọ Iṣẹgun ni ile ẹjọ naa ti kọkọ gbe aṣẹ kalẹ pe ẹgbẹ oṣelu PDP ko gbọdọ f'aye gba Obaseki lati dije labẹ aṣia rẹ.

Amọṣa ọrọ yi pada ni ọjọru nigba ti ile ẹjọ naa tẹti si ẹbẹ awọn igun mejeeji lati yanju aawọ naa ni tubiinubi laarin ara wọn

Obaseki: Kí ló dé tí Aàrẹ Buhari kìí fí í dá sí aáwò àwọn ọmọ ẹgbé APC?

Ni ọjọ Iṣẹgun ni ile ẹjọ naa ti kọkọ gbe aṣẹ kalẹ pe ẹgbẹ oṣelu PDP ko gbọdọ f'aye gba Obaseki lati dije labẹ aṣia rẹ.

Amọṣa ọrọ yi pada ni ọjọru nigba ti ile ẹjọ naa tẹti si ẹbẹ awọn igun mejeeji lati yanju aawọ naa ni tubiinubi laarin ara wọnIle ẹjọ giga apapọ ilẹẹwa to wa ni ilu Portharcourt ti fa iwe ẹjọ ti wọn pe tako iduro gomina Godwin Obaseki gẹgẹ bi oludije ni idibo abẹle fun ipo gomina lẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Edo.

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Presidency

Ọpọlọpọ aawọ lo ti waye laarin awọn oloye ẹgbẹ APC ati laarin awọn ọmọ ẹgbẹ APC lati igba ti ẹgbẹ yii ti bẹrẹ.

Awọn aawọ miran ni ko han pupọ sita nigba ti awọn miran di ranto mọ awọn ọmọ ẹgbẹ ti ọrọ kan lọwọ.

Koda, awọn aawọ miran ninu ẹgbẹ APC di eyi ti awọn ọmọ ẹgbẹ miran binu kuro fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ.

Eyi lo ṣokunfa ibeere nla pe kini ipa ti Aarẹ Buhari n ko ninu alaafia awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC?

Pabanbari rẹ wa ni ti Aawọ to waye ninu ẹgbẹ oselu All Progressive Congress (APC) laarin Gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki ati alaga ẹgbẹ Adams Oshiomole ni ipinlẹ Edo blọwọlọwọ.

Eyi to mu ki Obaseki kọwe fi ẹgbẹ silẹ lawọn kan sọ pe o fihan pe ẹnu Aarẹ Buhari ko ka ọrọ bo ti se le wu ko kere mọ ninu ẹgbẹ oselu rẹ.

Bawo ni o ti ṣe ṣẹlẹ?

Wọn ti kọkọ bẹrẹ pẹlu ikunsinu lorisiirisii.

O to ọjọ mẹta ti aawọ yi ti n rugbo bọ eyi to pada wa kangun si pe igbimọ ayẹwo ẹgbẹ sọ pe Gomina Obaseki ko tọ lẹni to yẹ ko gbe apoti ibo labẹ asia ẹgbẹ.

Eyi mu ki Obaseki tara sasa lọ ba Aarẹ Buhari lọjọ Isẹgun pẹlu erongba pe yoo ba wọn pẹtu si ede-aiyede yi.

Sugbọn pabo ni eyi ja si nitori kete to kuro nipade pẹlu aarẹ lo sọ fun awọn akọroyin pe oun yoo lọ si ẹgbẹ miran lati dije dupo lẹyin toun ba kọwe fi ẹgbẹ oselu APC silẹ.

Ki idamu to ba Gomina Obaseki to waye, awọn miran ti ni ipenija iru eyi tẹlẹ bi apẹrẹ Gomina Kano, Sẹnẹtọ Rabiu Kwankwaso ati ẹni to gba ipo lọwọ rẹ, Gomina Abdullahi Umar Ganduje.

Àkọlé fídíò, Yorùbá dùn lédè, sáré pé gbólóhùn yìí wò tóo bá dá ara rẹ lójú

Abẹwo ọmọ ẹgbẹ si Aarẹ Buhari, èso wo ló máa n bí?

Saaju ipade yi, awọn onwoye agbo oselu Naijiria ti n sọ pe abẹwo rẹ si Aarẹ ko ni yi ohun ti yoo ba sẹlẹ si i pada.

Wọn sọ eyi nitori pe a ti ri apẹrẹ ninu ẹgbẹ APC nibi ti awọn to kan si Aarẹ lati ba wọn wa wọrọkọ fi ṣada si ọrọ wọn ko mu ababọ daadaa pada wa sile.

Eyi ni wọn sọ pe bẹẹ naa ni Gomina Ambọde ati awọn miran ti ṣe abẹwo si Buahri ni Abuja ṣeyin ti ẹgbẹ si pada tun kọ ẹyin si wọn naa ni.

Bi i ti Obaseki, Ganduje sabẹwo si Aarẹ Buhari lati petu si aawọ laarin oun ati Gomina Ganduje sugbọn pabo lo ja si.

Kwankwaso pada fi APC silẹ lọ sinu PDP nigbẹyin ni

Idi ree ti ẹgbẹ APC fẹ fidi rẹmi ninu idibo ọdun 2019 nitori awọn to n se alatilẹyin fun Kwankwaso.

Bi a ko ba tun gbagbe iru nkan bayi naa waye laarin Gomina Akinwumi Ambode ipinlẹ Eko ati baba isalẹ ẹgbẹ APC Bola Ahmed Tinubu.

Wọn kẹjọ lọ ba Aarẹ Buhari sugbọn ko ribi yi ipinnu to wa nilẹ pada pe Ambode ko ni le dupo labẹ asia ẹgbẹ APC.

Ṣé lootọ ni Aarẹ Buhari ko lẹnu ninu ọrọ ẹgbẹ oṣelu APC?

Ọmọwe Abubakar Kari to jẹ onimọ nipa ẹkọ oselu to wa ni Fasiti Abuja sọ fun BBC pe Aarẹ Buhari ko lẹnu ninu ọrọ ẹgbẹ ni ipinlẹ rẹ ka to wa sọ pe lorileede Naijiria lapapọ.

O ni: "Aarẹ Muhammadu Buhari kii saba da si ọrọ aawọ yala ninu ẹgbẹ rẹ nipinlẹ to ti wa ni tabi lorile-ede Naijiria lapapọ.''

Àkọlé fídíò, Ìtàn Olaniyi Balogun, ọ̀jọ̀gbọ́n tó fi Nàìjíríà sílẹ̀ lọ gba iṣẹ̀ àgbẹ̀ l'Ámẹ́ríkà

Omọwe ni koda, Buhari kii da si ọrọ ẹgbẹ ni Daura to ti wa funra rẹ.

Omọwe naa ni : Bi a ko ba gbagbe bẹẹ lo se nigba to wa ninu ẹgbẹ oselu CPC lasiko ti aawọ n koju ẹgbẹ naa kaakiri ipinlẹ.

Koda, si ọrọ yi debi ti yoo yanju rẹ titi ti o fi wa sakoba fẹgbẹ naa lapapọ.''

Àkọlé fídíò, Toyin Ibietan: Àlòkù táyà ọkọ̀ ló mú mi rí nǹkan ṣe lásìkò ìgbélé COVID-19