Air India plane crash: Ìjàmbá bàálù India Express tó já ní Kerala pa èèyàn 16
Ọkọ baalu ofurufu ilẹ India to ko ero mọkanlelaadọwa ti ja ni papakọ ofurufu ilu Kerala.
Baalu naa gbera lati ilu Dubai, ni ẹsẹ rẹ tase lasiko to n gbiyanju lati balẹ ni papakọ ọkọ ofurufu Calicut.
Irinajo baalu naa jẹ ọkan lara eyi ti ijọba n ṣe lati ko awọn ọmọ orilẹ-ede India ti coronaviru se mọ ita pada sile.
Gẹgẹ bi awọn alasẹ nileesẹ ofurufu India sọ, ọkọ baalu ofurufu naa, lo yẹ kuro loju opo rẹ, to si pin si meji ni papakọ ofurufu Calicut ni kete to balẹ.
Eto idoola ẹmi ti n lọ lọwọ, tawọn oṣiṣẹ pajawiri si ti de ibi iṣẹlẹ naa.
Wọn ti ri pupọ ninu awọn eero baalu na yọ jade, ti ọpọ ninu wọn si ti di eero ile iwosan nitori bi wọn ṣe fi ara pa.
Ileesẹ BBC gbọ pe, o kere tan, eeyan mẹrindinlogun, to fi mọ awakọ ofurufu naa, lo ti jade laye.
Bakan naa, ọpọ ero inu baalu IX-1344 naa lo farapa, ti awọn ọmọde inu rẹ jẹ mẹwa, oṣiṣẹ baalu meji ati awakọ ofurufu meji.
Oludari eto irinna ofurufu nilẹ India ni ọkọ ofurufu naa lo ja sinu afonifoji kan, to si pin si meji ni kete to kuro loju opo rẹ.
Iṣẹlẹ naa to waye lasiko iji ojo lile to n waye lẹkun naa, ni deede aago meji abọ ọsan.
Ẹkun omi ati ilẹ mimi lo ti n waye nibẹ lọwọ lọwọ.














