India: Ó lé ní mílíọ́nù ènìyàn tí wọ́n kó kúrò lágbèègbè Orissa

Oríṣun àwòrán, Reuters
Iji lile Cyclone Fani ti da ijamba silẹ ni ila-oorun orilẹede India, ti ọpọlọpọ ile si ti wo lagbeegbe naa.
Ajọ to n risi ọrọ oju ọjọ ni iji lile Cyclone Fani ni agbeegbe Orissa, ti wọn tun n pe ni Odisha lo wa ni ọgangan ibi ti iji lile naa n gba.
O le ni miliọnu eniyan ti wọn ti ko kuro ni agbeegbe Orissa naa, ti wọn si ti ko wọn lo si awọn ilu miran ti iji lile naa ko de.
Awọn osisẹ pajawiri ni ojo lile ti sẹlẹ lawọn ibi kan, ti ọpọlọpọ orule si ti ba iji lile naa lo, amọ ko si ẹni ti o padanu ẹmi wọn.
Bakan naa ni awọn ilu to wa lagbeegbe Puri ati agbeegbe miran n ri atẹkun lile to to iwọn 175 km/h (108mph) ati 200 km/h.

Ti a ko ba gbagbe, orilẹede India si n se idibo gbogboogbo lọwọ, eyi to bẹrẹ ni osu to kọja, ti yoo si wa sopin ni ipari osu yii.









