Ikú Caruana Daphne: Bí mo ṣe jà fún ìdájọ́ òdodo lórí ìyá mi tí wọ́n ṣekú pa

Oríṣun àwòrán, Reuters
- Author, Matthew Caruana Galizia
- Role, World Press Freedom Day
Nigba kọọkan, mo ni lati joko si inu yara kan lati jiroro pẹlu ẹni to n ṣe iwadii iku to pa iya mi.
Igba akọkọ ti idile wa pade rẹ ni ọdun mẹfa ṣeyin nigba to wa sile wa lati wa gbe ti mọle.
Nigba naa lọun, iya mi ti kọ itan kan lori ayelujara ninu eyi to ti fi oludije ipo aarẹ kan ṣe yẹyẹ ni ọjọ idibo. Ọkan lara awọn alatilẹyin rẹ si fi ẹjọ sun ọlọpaa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Nitori naa, ọlọpaa naa wa sile wa ni ọganjọ oru lati wa gbe iya mi ti mọle fun ẹsun kan ti wọn pe ni fifi ero ti ti ofin ko gba laaye han.
Ibi ti mo ti n ṣiṣẹ nigba naa jina. Awọn eniyan si n fi fidio bi wọn se da silẹ ni ihamọ ọlọpaa ni bi aago kan aabọ oru.
Wakati diẹ lẹyin iṣẹlẹ ọun, o tun ti pada sori ayelujara lati fi ero rẹ han lori bi wọn ṣe fiya jẹ yii. Iya mi tilẹ tuin fi oludije naa.
Nibayii, ọkunrin to wa mu iya mi lọ agọ ọlọpaa ni ọjọ naa ni o wa n ṣe iwadi iku rẹ bayii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni ọjọ ti wọn pa iya mi, Daphne Caruana Galizia, o wa ọkọ lọ ile ifowopamọ lati lọ yanju ọrọ kan nipa apo ifowopamọ rẹ ti minisita kan ti ni ki ileeṣẹ naa ti pa.
O ṣẹṣẹ pe ẹni ọdun mẹtalelaadọta, to si ti de oke tente aye rẹ gẹgẹ bii akọrọyin to ti ṣiṣẹ fun ọgbọn ọdun.
Kilo TNT (ti wọn fi n ṣe ado oloro) ti wọn ti fi pamọ si abẹ ọkọ rẹ bu gbamu.
Ọpọlọpọ awọn alatilẹyin ijọba ni o n dunu lori iku iya mi ni gbangba.
Àwọn kan tilẹ ni emi ni o gbimọ lati pa iya mi tabi pe ohun lo fira rẹ wewu.

Iku Daphne Caruana Galizia
- Oṣu kẹwaa 2017: Akọroyin oniwadii Daphne Caruana Galizia ku ninu ado oloro ti wọn fi sinu ọkọ.
- Adari ijọba Joseph Muscat ni nkan buburu ni ikọlu naa. Awọn ẹbi oloogbe ni ko si awọn oloṣelu kankan ni Malta to gbọdọ wa sibi isinku rẹ.
- Oṣu kejila 2017: Awọn agbofinro mu eniyan mẹta. Awọn oluwadii si ni o ṣeeṣe ki wọn lo awọn apani-gbowo.
- Oṣu keje 2018: Igbimọ oluwadii ti ijọba Malta gbe kalẹ ti agbẹjọro kan si dari ni adari ijọba ati iyawo rẹ ko jẹbi ẹsun jẹgudujẹra ti Daphne Caruana Galizia fi kan wọn.
- Oṣu kẹjọ 2018: Awọn ẹbi Daphne Caruana Galizia beere fun iwadii kikun lati wo boya Malta i ba le dena iku rẹ.

Kilode ti awọn ipaniyan wọnyi ṣe pataki?
"Fifi ero han lai si wahala ni irinṣẹ awọn akọroyin. O si maa mu ilu to ni alaafia wa." Oun ti aburo mi sọ fun awọn aṣoju orilẹede Gẹẹsi kan ree nigba ti ṣi n ṣọfọ iya mi.
Lẹyin ti iya wa ku, oun kan ṣoṣo to ran wa lọrọ ni ikẹdun ati ọfọ ti awọn oriṣiriṣi eniyan fi han.
O ya mi lẹnu, o si mu oun kan ti ọrẹ mi kan sọ fun mi wa sọkan mi. O ni, "Awọn eniyan daradara wa kaakiri; ọ gbọdọ wa wọn kan."
O wu mi lati gbe ilu ti ko si idena kankan, ti ofin si wa fun gbogbo eniyan, ti wọn si n bọwọ fun ẹtọ ọmọ eniyan.
Ọrọ ti maa n pẹju ti awọn eniyan buruku laarin ilu ba gba agbara.
Iṣẹ ti awọn aburo mi, baba mi ati emi ti file ara wa lọwọ lati igba ti wọn ti pa iya mi ni lati wa idajọ fun ipaniyan rẹ, ki a si ri pe nkan bi eyi ko ṣẹlẹ mọ.
Asiko ko si fun oun miiran.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni aarin idile mi, igba miiran, a maa n sọrọ nipa bi a ko ṣe le ni suuru fu ki kawọ gbera awọn eniyan kan to wa ni ipo agbara.
Awọn ọmọ akọroyin oluwadii bii ti iya mi, Ugur Mumcu, sọ fun mi wipe lẹyin ti ado oloro ti wọn fi pamọ sinu ọkọ pa baba wọn, ọga ọlọpaa ilu naa kọ lati ṣe iwadii lori iku naa. O ni, "E woo, ko si oun ti mo le ṣe. Ogiri nla kan wa niwaju mi."
Iya wọn si fesi fun wọn wipe, "Ẹ bẹrẹ si ni yọ ogiri naa ni ẹyọ kọọkan, titi yoo fi wo palẹ."
Oun ti o n ran wa lọwọ lati igba ti iya wa ti ku ree.
A gbọdọ ri wipe ayipada de. A si ti fọwọsowọpọ pẹlu awọn miiran lati ri pe a wu aisan ki eniyan ma ni ominira lati fi ero rẹ han, ki a si fi igba tuntun han gbogbo aye.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ki i ṣe awa nikan ni ọrọ yii wa lọwọ wa lati doju kọ ọrọ yii: awọn ẹbi, ara, ọrẹ ati awọn ololufẹ awọn akọroyin ti wọn ti pa tabi ti wọn gbe si atimọle.
Ọrọ nla yii lagbara gan, a ko sile da nikan gbe. Gbogbo eniyan ni gbogbo ibi gbudọ dara pọ mọ wa.everywhere to join us.

Ayajọ ọjọ ominiran awọn oniroyin
- Ayajọ ọjọ ominiran awọn oniroyin ni ajọ Iṣọkan Agbaye da silẹ ni ọdun 1993 ti wọn si maa n ṣe ayẹyẹ rẹ ni ọjọ kẹta oṣu karun un ni ọdọọdun.
- Akori ti ọdun yii ni Iṣẹ iroyin ati idibo ni akoko ti iroyin ofege pọ nita.
- Ajọdun yii wa lati da inu dun ki a si gboriyin fun awọn akọroyin ti o ti padanu ẹmi wọn lẹnu iṣẹ.
- Ni ọdun to kọja, akọroyin marundinlọgọrun ni wọn pa, gẹgẹ bii ajọ awọn akọroyin lagbaaye, IFJ sọ.

Mo mọ wipe ọpọlọpọ ni yoo ranti bi gbogbo aye ṣe fẹran akọroyin ọmọ Saudi Jamal Khashoggi.
Eniyan kan ṣoṣo ni o korira rẹ debi to fi le pa.
Ninu gbogbo ipaniyan yii, ati ti iya mi, ko si ẹri wipe awọn ijọba n gbe igbesẹ kankan lati ran awọn to ṣiṣẹ naa lọ ẹwọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
A ti n yọ okuta idena to wa niwaju wa diẹdiẹ bayii. A ti pe fun iwadii nipa oun to ṣẹlẹ ti ko fi jẹ ki wọn dena ipaniyan akọroyin to lokiki ju ni Malta.
Ni ojoojumọ, mo maa ni ireti wipe oun ti iya mi fẹmi rẹ lelẹ fun ni orukọ orilẹedemi yoo wa si imuṣẹ ni oju mi.
Oun ti iya mi ko le mọ bayii ni bi iku rẹ ṣe mu iwuri ba ẹgbẹgbẹrun awọn eniyan ni Malta ati awọn ibo miiran.
Iwuri yii si jẹ mu aabo ba ọpọlọpọ awọn akọroyin ti wọn ko ku iru iku to pa iya mi.

Nipa iroyin yii:
Matthew Caruana Galizia jẹ akọroyin oluwadii ati ọmọ akọroyin Daphne Caruana Galizia, wi wọn fi ado oloro inu ọkọ pa ni oṣu kẹwaa ọdun 2017. Ẹ le tẹle ni ori Twitter here.













