Samuel Ogundipe: Níní ìwé àṣíri ìjọba lọ́wọ́ lọ́nà àìtọ́ ni ẹṣẹ rẹ̀

Samuel Ogundipe

Oríṣun àwòrán, Twitter/Samuel Ogundipe

Àkọlé àwòrán, Akọròyìn Samuel Ogundipe wà ní ahámọ́ àwọn ọlọ́pàá

Ilé iṣẹ́ ọlọpàá Nàìjíríà ní Samuel Ogundipe tí àwọn gbé lọ sí ilé ẹjọ́ ni àwọn fi ẹ̀sùn olè kàn.

Ati pé o ní iwe àṣíri níkawọ lọ́nà àìtọ ní èyí to lè gbógunti ààbo, àláàfíà tó tun le dá rògbòdiyan sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè yìí ni àwọn fi kan an.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bákan náà ní ilé-iṣẹ́ ọlọpàá tun ni àwọn ń fọjú ẹ ba ilé ẹjọ nítorí pe àwọn tun fi ẹsun kàn-án pé ó tẹ ojú ofin láti tú àṣírí tí kò yẹ kó tú, pẹlú ṣíṣẹ̀ sí ofin ori ayélujara, ni èyi ti o ti jẹ́wọ si tí o si ti ṣetan láti jẹjọ.

Ilé-iṣẹ́ ọlọpàá ní àwọn kìí ṣe arúfin súgbọn àwọn máa ń lépa ohun ti o máa ń mú ki ìjọba awa-ara-wa gbópọn síi. Ilé -ìṣẹ́ ọlọpàá rọ ará ìlú láti máa kọbiara sí àhesọ to gbòde kan láti ba orúkọ ọlọpàá jẹ́ lóri ọ̀rọ̀ náà.

Kíló fàdí abájọ ti Ọlọ́pàá fi gbé akọ̀ròyin lọ ilẹ́ ẹjọ́ ni ìkọ̀kọ̀

Ileeṣẹ ọlọpaa ti gbe Samuel Ogundipẹ, akọroyin iwe iroyin Premium Times ti wọn mu lori iroyin kan to kọ lọ ile ẹjọ bayii.

Wọn ko jẹ ki ẹni kankan mọ bẹẹ si ni wọn ko jẹ ko ni agbẹjọro. Ile ẹjọ magistrati to wa ni Kubwa ni wọn gbe e lọ lori ẹsun jija ileeṣẹ ọlọpàá lole.

Iroyin sọ wi pe, Ogundipe ti kọkọ sọ fun awọn ọlọpàá naa pe oun ni lati ba agbẹjọro sọrọ ki oun to le lọ ile ẹjọ. Sugbọn nigba ti wọn gbe e de ile ẹjọ wọn ko jẹ ki adajọ mọ pe oniroyin ni.

Adajọ naa wa ni ọlọpaa ṣi le gbe Ogundipe ti mọle fun ọjọ marun miiran.

Àkọlé fídíò, SARS ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti yọ àwọn ọ̀bàyéjẹ́ kúro

Ero awọn eniyan Naijiria lori ọrọ naa

Ọgọọrọ ajafẹtọ ọmọniyan ati awọn ile iṣẹ iroyin nile ati loke okun ni wọn ti bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu bi awọn ọlọpaa ti fi akoroyin eto aabo, amuel Ogundipe, fun iwe iroyin Premiun Times s'ahamọ

Bakan naa, awọn oṣiṣẹ meji iwe iroyin naa, Musikilu Mojeed to jẹ olootu iroyin ati akọroyin eto ẹkọ, Azeezat Adedigba, naa kọkọ wa latimọle awọn ọlọpaa SARS ki wọn to dawọn silẹ.

Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe ko sọ ibi ti o ti ri iroyin kan to kọ ṣugbọn o kọ lati sọ ọ fun wọn.

Ibeere to wa lọkan àwọn akọroyin ni pe ṣe a kò gbodo gbe iroyin iṣẹ iwadii to ba ti ṣe lodi si ọlọpaa tabi ijọba sita mọ ni?

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Ọdún 1940 ni wọ́n ti ń sin ọ̀ọ̀nì ilé Delesolu ní Ìbàdàn

Wo diẹ lara awọn oniroyin lorilẹ-ede Naijiria ti awọn ọlọpaa ti mu tabi dunkoko mọ ri:

Ibraheema Yakubu, ti oun naa jẹ oniroyin pẹlu Hausa DW radio lugbadi awọn ọlọpaa nibi ti o ti n kọroyin lori iwọde wọọrọwọ ẹgbẹ musulumi nilu Kaduna lọdun 2017.

Yakubu ni awọn ọlọpaa kọkọ fiya jẹ oun ki wọn to mu oun lọ.

Ibraheema yakubu

Oríṣun àwòrán, Facebook/Ibraheema yakubu

Àkọlé àwòrán, Ibraheema Yakubu náà wà lára àwọn oníròyìn tí wọ́n fara káasá ìkolù àwọn ọlọ́pàá

Awọn ọlọpaa kọkọ fiya jẹ oniroyin meji, iyẹn, ọgbẹni Daniel Elombah ati ọgbẹni Tim Elombah ti wọn n ba ile iṣẹ iroyin ayelukara kan ṣiṣẹ ki wọn to mu wọn ni ọjọ kinni, oṣu kinni, ọdun 2018 nilu Nnewi, ipinlẹ Anambra.

Wọn ni pe ẹṣẹ ti wọn ṣẹ ni iroyin kan lori ọga ọlọpaa Naijiria, Ibrahim Idris ti ko tẹ awọn ọlọpaa lọrun.

Daniel Elombah

Oríṣun àwòrán, Facebook/Daniel Elombah

Àkọlé àwòrán, Ìpínlẹ̀ Anambra ni àwọn ọlapàá ti kọlu ọ̀gbẹ́ni Daniel Elombah

Awọn ọlọpaa tun dunkoko mọ ọbinrin akọroyin Michaela Moye ti o n ba iwe iroyin Daily Times ṣiṣẹ wi pe o n ya fọto bi wọn ti n wole nilu Abuja lọdun 2011.

Wọn kọkọ fiya jẹ ẹ ki wọn to fi agidi ni wọn fi gba kamẹra mọ lọwọ rẹ.

Michaela Moye

Oríṣun àwòrán, Twitter/Michaela Moye

Àkọlé àwòrán, Ọlọrun ló yọ Michaela Moye lẹ́yìn tí àwọn ọlọ́pàá gba kámẹ́rà lọ́wọ́ rẹ̀

Awọn ọlọpaa kọkọ fiya jẹ Segun Salami to n ba Channels Television ṣiṣẹ nile ijọba ipinlẹ Kogi ki wọn to mu u ni ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2017 ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ nilu Lokoja

Segun Salami

Oríṣun àwòrán, Facebook/Segun Salami

Àkọlé àwòrán, Àwọn ọlapàá ilé ìjọba ìpínlẹ̀ Kogi ni wọ́n kọlù oníròyìn Segun Salami

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amin iyasọtọ kan
Àkọlé fídíò, 'Ọ̀lọ́wọ́ òsì kọ́ndọ́rọ́'