Bunmi Ojo: Ó ń wòran bọ́ọ́lù lọ́wọ́ ni àgbébọn sekú pàá

Aworan Bunmi Ojo

Oríṣun àwòrán, Facebook/Bunmi.ojo.

Àkọlé àwòrán, Ilumọka oloseelu ni Bunmi Ojo jẹ nipinlẹ Ekiti

Àwọn agbebon kan tí ṣeku pá arákùnrin Bunmi Ojo nílu Ado Ekiti, níbi tí ọ ti n wò bọọlu lójó ẹtì.

Ọgbẹni Bunmi Ojo, tó ti figba kàn jẹ olùrànlọwọ fun Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì tẹlẹri, Segun Ọni pàdé ikú rè nibudo igbafẹ to wa ni Ajitadundun ladugbo Adebayo nilu Ado Ekiti nibi ti o ti n wò ifẹsẹwọnsẹ Premiership láàrin Manchester United ati Leicester City.

Ninu igbinyanju BBC Yoruba lati fi idi isẹlẹ yii mulẹ lo mu ka pe alukoro fun ileesẹ ọlọpa nípinlẹ Ekiti, DSP Caleb Ikechukwu, ẹni to sọ pé àwọn kò tí gbọ nipa iṣẹlẹ òhun.

Ṣugbọn awọn kan ti ọrọ náà sójú wọn sọ fún BBC Yoruba pe, looto ni isẹlẹ naa waye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Sunday Adelaja: Tẹ́tẹ́ làwọn pásítọ̀ tó ń gba owó ‘ìserere’ ń ta

Adekunle Omega, to je olugbe ilu Ado sọ pe ẹni mimọ si oun ni Bunmi Ojo, ti iroyin iku rẹ si jẹ ohun ti o ba ni lọkan jẹ.

''Gbogbo igba ti wọn ba wa sile lati Abuja ni wọn ma n sere pẹlu awọn onisẹ ọwọ mẹkaniki wọn, ni aaye igbafe to wa ladugbo Ajitadundun. Eeeyan daada ni wọn''

Adekunle sọ fun ile isẹ BBC Yoruba wi pe, gbogbo eeyan to mọ Bunmi Ojo, to jẹ Komisana to n soju ipinlẹ Ekiti ninu ajo to n risi igbesẹ aparo kan ko gbọdo ga ju ọkan lọ lorileede Naijiria, (Federal Character Commission) ni iroyin iku rẹ dun.

Bakan naa ni BBC Yoruba kan si Oloye Sẹgun Oni, lati fidi isẹlẹ yii mulẹ, o ni lootọ ni amugbalẹgbẹ oun nigba kanri naa ti jalaisi, ti iku rẹ si ka oun lara pupọ, amọ oun ko tii lee sọrọ kankan lori isẹlẹ yii.

Loju opo Facebook Ogbeni Bunmi Ojo, isẹ ibanikẹdun orisirisi lawọn eeyan ko sibẹ.

Aworan Ikini ikẹdun loju opo Facebook Bunmi Ojo

Oríṣun àwòrán, Facebook/Adenitan Akinola

Àkọlé àwòrán, Ikini ikẹdun loju opo Facebook Bunmi Ojo
Aworan Ikini ikẹdun loju opo Facebook Bunmi Ojo

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/AKOLAWOLE GBENGA

Àkọlé àwòrán, Ikini ikẹdun loju opo Facebook Bunmi Ojo

Ko ti daju idi ti awọn agbebon naa fi pa Bunmi Ojo.

Ni kete ti a ba gborọ lẹnu agbenuso ile isẹ ọlọpa nipinle Ekiti, ni a o jabọ fun yin.