Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá: Ọlọ́pàá tó yìnbọn l'Ékìtì, olóṣèlú tó rán níṣẹ́ yóò délé ẹjọ́

Ọlọpa kan gbe ibọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìgbésẹ̀ ń lọ láti pèsè ètò àbò tó dúró digbí fún ìdìbò

Ileeṣẹ ọlọpa ti yọ ọlọpa to yinbọn nileeṣẹ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ekit ni ọsẹ to kọja niṣẹ.

Ọlọpa naa yinbọn lasiko ipade ikinikaabọ itagbangba ti wọn ṣe fun oludije ipo gomina lẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ, Kayọde Fayẹmi kaabọ nilu Ado Ekiti eleyi to ba ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣofin apapọ tẹlẹri, Micheal Ọpẹyẹmi Bamidele ati eeyan marun un miiran.

Kọmiṣọna ọlọpa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Bello Mohammed lo sọ ọrọ yii di mimọ nilu Ado Ekiti lọjọ aje.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kọmiṣọna ọlọpa, Bello Mohammed ni, 'wọn ti yọ ọlọpa ti aje iṣẹlẹ naa ṣi mọ lori kuro lẹnu iṣẹ bi o tilẹ jẹ pe ara rẹ kun fun ọpọlọpọ ọgbẹ bayii 'sugbọn nigba to ba ya yoo foju wina ofin bi o ti tọ́, gbogbo araalu ni yoo si maa gbọ bi ọrọ ba ṣe n lọ si.'

Kọmiṣọna ọlọpa nipinlẹ Ekiti tun fi kun un pe oloṣelu to mu ọlọpaa naa wa sibi ipade naa pẹlu wa lahamọ ọlọpa yoo si foju bale ẹjọ ti asiko ba ti to.