Ẹgbé òsèlú APC ní Ekiti dáwọ́ ìpolongo ìdìbò Gómìnà dúró

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ òṣèlú APC ti fi adagba ètò ìpolongo ìdìbò fún ipò Gómìnà wọn ni ìpínlè Ekiti rọ̀ ná.
Ìpolongo náà tó yẹ kí ọ wáyé ni ọjọ ajé ni wọ́n ni sun sí iwájú títí di ìgbà tí àwọn ọlọ́pàá yóò lè pèsè ààbò tó péye fún wọn.
Ìròyìn ti ile iṣẹ ìròyìn News Agency of Nigeria gbé sọ wí pé alága ẹgbẹ APC ni ipinle Ekiti, Jide Awe sọ pé isunsiwaju náà ní ṣe pẹlú ìsẹ̀lẹ̀ ìyìnbọn to wáyé láìpẹ́ yìí ní ìpínlẹ̀ náà.
Ọ tẹnumọ ọ pe ìsẹ̀lẹ̀ ìyìnbọn to wáyé kìí se àṣìṣe bi kíì ṣe pé wọn fẹ pa Kayode Fayemi tó jẹ Oludije ẹgbẹ́ awọn ni.


Oríṣun àwòrán, Facebook/APC Ekiti

Ṣugbọn ile iṣé ọlọ́pàá nínú esi ìwádìí ti wọn gbe jade lọ́jọ́ àbámẹ́ta sọ pé àṣìṣe ni ìsẹ̀lẹ̀ ìyìnbọn náà .
Alukoro ile iṣé ọlọ́pàá , DSP Caleb Chukwuemeka sọ pe ''a ti mú ọlọ́pàá to yin ìbon náà.''
''Ìlú Eko ní ayé iṣẹ́ re wa ṣugbọn ọ wá ṣé ìṣe àlùmọ̀kọ́rọ́yí ni Ekiti pẹlú olóṣèlú kàn ní.''
O fi kun un pe àwọn tó f'arapa nínú ìṣẹlẹ náà n gba ìtọjú ni ile ìwòsan nígbà tí ọlopaa ọ̀ún wa ni ìtọ́jú lábẹ́lé.














