Opeyemi Bamidele fara gbọgbẹ́ níbi ìwọ́de fún Fayẹmi

Oríṣun àwòrán, @repbamidele
Eniyan kan ti ku ti ọpọ eniyan si fara pa ninu isẹlẹ iyinbọn to waye ni ibi igbalejo tí wọ́n se fún Kayọde Fayemi,oludije ipo Gomina ni ipinle Ekiti.
Olu ile ẹgbé oselu APC to wà ní Ado-Ekiti ni isẹlẹ naa ti waye.
Lara awon to farapa ni ibi isele naa ni Opeyemi Bamidele, to jẹ ọmọ asoju ile asofin orileede Naijiria ana ni ipinle Ekiti.
Ọkan lara awọn amugbalẹgbe Bamidele fun eto iroyin, Ahmed Salami, sọ fun BBC Yoruba pe, ni ibi igbalejo ti wọn n se fun Kayode Fayemi, ẹni to jawe olubori ninu idibo abẹle ẹgbẹ oselu APC to kọja ni Ipinlẹ Ekit,i ni ìṣẹlẹ náà ti ṣẹlẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Salami ni, Bamidele ti n gba itọju bayii ni ile iwosan ijọba ipinlẹ to wa ni Ado-Ekiti ati pe ikun ati ẹsẹ ni ọta ibọn naa ti baa

Oríṣun àwòrán, @repbamidele
Bẹẹ ba gbagbe, Bamidele jẹ ọkan lara awọn oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oselu APC ti Kayọde Fayemi bori wọn, ninu idibo abẹle APC to kọja naa.
Iroyin to tẹ wa lọwọ ni, wahala kan bẹ silẹ ni ibi igbalejo Fayemi, nigba ti janduku kan bẹrẹ si ni lọ ibọn mọ ọlọpaa kan lọwọ, ni ibọn naa ba ro kùù, ti ọta si fọn jade,eyi to lọ ba Bamidele.








