Ikú kò jẹ́ ki Tunrayọ Adeoye ri òpin Ramadan

Oríṣun àwòrán, Kola carew Facebook
Gbajugbaja osere Nollywood, Motunrayo Adeoye, ti jade laye lasiko aisan ọgbe inu to ti n baa finra fun ọjọ gbọọrọ ni ilu Ibadan.
Iroyin jade pe, agba obinrin osere naa jade laye lowurọ Ọjọ Ẹti, ọjọ kinni, osu kẹfa.

Oríṣun àwòrán, @naijapalsf/b
Wọn ti sin Tunrayọ Adeoye ni ile rẹ to wa ladugbo Akobọ ni ilu Ibadan, nilana ẹsin musulumi.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Nigba aye rẹ, obinrin naa jẹ gbajugbaja ninu ẹgbẹ osere Yoruba, ati wipe, o tun jẹ ọkan lara awọn ilumọọka ninu ẹgbẹ awọn osere.
Igbe aye Motunrayo Adeoye
Ni igba aye rẹ, Motunrayo jẹ ibatan alaafin ti Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyemi kẹta.
Arabinrin naa kawe gboye ni ileẹkọ ẹkọsẹ ọwọ ti Osogbo Technical College ni ipinlẹ Osun, nibi to ti kọ nipa imọ ẹrọ, ki oto sẹ sẹ wa lo si orilẹede Switzerland fun Osu meje lati lo kọ ẹkọ gboye nipa imọ ẹrọ.
Lẹyin ọdun 1970 ni gbajugbaja osere naa darapọ mọ ile-isẹ iroyin ti ipinlẹ Ọyọ, BCOS gẹgẹbi onimọ nipa ẹrọ ati igbohunsafẹfẹ.

Oríṣun àwòrán, Kola Carew Facebook
Isẹ naa lo se fun ọgọji ọdun ko to di wi pe o fẹhinti lọdun 2010.
Lẹyin igba yi ni o darapọ mọ awọn olosere Nollywood., ọkan lara awọn ere to se to fi di ilumọọka ni fiimu kan ti wn pe ni igbekun.













