Ọmọge Campus fi ọmọ meji saye lọ

Aisha Abimbọla
Àkọlé àwòrán, Oun si ni ọmọ kẹta tawọn obi rẹ yoo bi lẹyin ibeji to siwaju rẹ, eyiti Yoruba n pe ni Idowu.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbogbo ọmọ Naijiria to gbọ nipa iku ojiji to pa gbaju-gbaja osere tiata ni, Aisha Abimbọla, ti ọpọ eeyan mọ si Ọmọge Campus ni ara wọn bu mọ asọ, ti wọn si n se idaro ololufẹ wọn lori itage naa.

Taa ni Aisha Abimbọla?

Ọjọ kọkandinlogun osu kejila ni ọjọ ibi Aishat Abimbọla, tii se osere tiata, akọtan, olootu ere tiata ati olokoowo.

Oun si ni ọmọ kẹta tawọn obi rẹ yoo bi lẹyin ibeji to siwaju rẹ, eyiti Yoruba n pe ni Idowu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Ọ̀gá Bello: Ikú Aisha Abimbọla ká wa lára

Ọmọ bibi ilu Ẹpẹ ni ipinlẹ Eko ni oloogbe Aisha Abimbọla, to si bi ọmọ meji. Ọgbẹni Musa Ibrahim ni Aisha ba se igbeyawo nigba aye rẹ.

Ọdun 2001 si ni Aisha dara pọ mọ awọn osere tiata, lara ere sinima to se, eyi to mu ko ni okiki pupọ ni Ọmọge Campus.

Ile ẹkọ gbogbo-nse Poly ti ipinlẹ Eko ni Aisha ti kawer, to si gba iwe ẹri imọ nipa itọju ile itura, ti wọn n pe ni Hotel Management. Sugbọn oloogbe naa ko lo iwe ẹri yii rara lati fi jẹun, isẹ sise ere tiata lo gbajumọ julọ.

Aisha Abimbọla

Oríṣun àwòrán, Adedayo Owolabi

Àkọlé àwòrán, Lati ile ẹkọ alakọbẹrẹ́ ni Aisha ti bẹrẹ si ni se ere ori itage,

Aisha tun n se oloyinbo

A si lee sọ pe lati ile ẹkọ alakọbẹrẹ́ ni Aisha ti bẹrẹ si ni se ere ori itage, ere itage to si kọkọ se ni wọn n pe ni ‘Awerijaye’.

Bakan naa lo ti kopa ninu awọn ere onise ti oloyinbo bii ‘No pain no gain’ ati ‘So wrong so right, to si ko ipa arabinrin Camson nibẹ.

Ọpọ osere tiata n sedaro akẹẹgbẹ wọn to lọ

Yoruba ni ti ọdẹ ba ku, ọdẹ nii soro lẹyin ọdẹ. Ọpọ awọn osere ori itage nilẹ Naijiria lo ti n yanu silẹ, lai lee pa de mọ, lori iku ojiji pa Aisha Abimbọla.

Gbogbo awọn oju opo ayelujara si lo ti kun nipa iroyin agbọsọgba nu naa.

Ni oju opo Instagram, ọpọ ibanikẹdun lo kun ibẹ nipa iku Ọmọge Campus. Diẹ lara rẹ si ni iwọn yii.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

Skip Instagram post, 3
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 3

Idaro yii ko yọ oju opo Twitter silẹ, nitori n se lawọn ọmọ Naijira n se paga nipa iku Aisha Abimbọla.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Skip X post, 2

End of X post, 2