Amòfin: Nínà ojoojúmọ́ lé mu kí ìyàwó pa ọkọ rẹ̀

Ọbẹ

Oríṣun àwòrán, CC

Àkọlé àwòrán, Ara ìwà ipá ni sísọ ọ̀rọ̀ kòbákùngbé síra ẹni, tàbí fífi ọ̀rọ̀ èébú ránṣẹ́ sí òbí ọkọ tàbí ìyàwò ẹni.

Kìí ṣe tuntun fún tọkọ-taya láti ní gbólóhùn asọ̀ láàrin ara wọn, ṣùgbọ́n kàyéèfì tó wà níbẹ̀ ni pe, kí irú àáwọ́ bẹ̀ maa yọrí sí ikú tàbí ìfarapa.

Láyé ìgbà kan, ọkùnrin ni a ṣábà maa n gbọ́ pé, ó lu ìyàwó rẹ̀, ṣùgbọ́n lóde òní, ìròyìn nípa àwọn òbìnrin tó n lu ọkọ wọn nàá tí n jáde.

Láti bi i ọdún mélòó sẹ́yìn, ni ìròyìn ń gbalẹ̀ kan nípa bi ọkọ tàbí ìyàwó ṣe n pàdánù ẹ̀yà ara wọn lásìkò tí ìjà bá n wáyé láàrin tọkọ-taya, tí àwọn mìí tilẹ̀ n pàdánù ẹ̀mí wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amòfin kan tó tún jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ àwọn obìnrin, Abiade Abiala, nígbà tó n bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀, ṣàlàyé oríṣiríṣi ìwà ipá tó wà.

Abiade Abiala

Oríṣun àwòrán, Facebook/Abiade Abiola

Àkọlé àwòrán, Ìmọ̀ràn rẹ̀ ni pé níṣe ló yẹ kí ọkọ àti ìyàwó tó bá n la ìwà ipá kọjá wá ọ̀nà láti ṣàtúnṣe.

Àwọn ohun tó ń fa ìwa ipá

  • Sísọ ọ̀rọ̀ kòbákùngbé síra ẹni, tàbí fífi ọ̀rọ̀ èébú ránṣẹ́ sí òbí ọkọ tàbí ìyàwò ẹni.
  • Àì fi owó oúnjẹ sílẹ̀ fún ìyàwó nítori pé ó sẹ ọkọ.
  • Kódà, àìbìkítà fún ẹ̀tọ́ tàbí ifẹ́ inú ẹnìkejì lásìkò ìbálòpọ̀ nàá wà lára lílo ìwà ipá nínú ìgbeyàwó.
  • Ọkùnrin tó bá ní kí ìyàwó òun máà ṣiṣẹ́ tàbí tó n gba owó lọ́wọ́ ìyàwó lọ́nà àìtọ́.

Kí ló lé mú obìnrin pa ọkọ rẹ̀?

  • Kí àwọn òbí ẹni máse fọwọ́ sí kíkọ́ra ẹni sílẹ̀ lẹ́yìn tí ìgbéyàwó ti pin obìnrin lẹ́mìí.
  • Ìbẹ̀rù ojú tí àwùjọ yóò fi wo ni.
  • Obìnrin míi maa n fínnú-fíndọ̀ dúró sínú irú ìgbéyàwó bẹ̀ẹ̀ nítorí 'ẹ̀jẹ́ tí wọ́n ti bá ọkàn wọn dá pé àwọn kò ní fẹ́ ju ọkọ kan tàbí bímọ fún ju ọkùnrin kan lọ.’
  • Ìpolongo àti ìlani lọ́yẹ̀ tó ti pọ̀ si lójẹ́ kí àwọn òbinrin maa maa gbẹ̀san ìwà ipá tí ọkùnrin bá wù sí wọn.
  • Àti pé bí àwọn ìyàwó ilé nàá ti ṣe n ṣiṣẹ́ n fún wọn ní ìgboyà láti 'gbèjà' ara wọn.
  • Àti pé ọpọ̀lọpọ̀ obìnrin ti rí nkan tójú àwọn tó bá ara wọn nínú irú ìgbeyàwó bẹ́ẹ̀ n rí, ni wọ́n ṣe n fi ọ̀rọ̀ ṣe 'ẹní yára ni ògún n gbè.

Ìmọ̀ràn fún tọkọ-taya

Ó wá gba tọkọtaya ní ìmọ̀ràn pé, n ṣe ló yẹ kí ọkọ àti ìyàwó tó bá n la irú nkan bẹ́ẹ̀ kọjá wá ọ̀nà láti ṣàtúnṣe.

Àti pé, kí gbogbo ènìyàn àwùjọ mọ̀ pé, bí àwọn obìnrin nàá ti ṣe n gba ara wọn sílẹ̀, tí àwọn mì í tilẹ̀ n ṣekú pa ọkọ wọn, n fihàn pé, àsìkò ti tó láti fi òpin sí irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀, àti láti wá ọ̀nà tí nkan kò fi ní bàjẹ́ ju bóṣe wà lọ.