Buhari: Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ padà wa díje lẹ́yìn mi ní 2019

Buhari n buwọlu abadofin 'Not too young to run'

Oríṣun àwòrán, NIGERIA PRESIDENCY

Àkọlé àwòrán, Muhammadu Buhari ti bu ọwọ́ lu àbádòfin tì ó fààyè gba àwọn ọdọ́ láti du ipò kípò tó wù wọ́n ni Nàìjíríà
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Èrò àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣọ̀tọ̀ọ́tọ̀ lórí àbá òfin tì ó fààyè gba àwọn ọdọ́ láti du ipò kípò tí ó bá wù wọ́n, #NotTooYoungToRun, èyí tí Ààrẹ Muhammadu Buhari ṣẹ̀ṣẹ̀ bu ọwọ́ lu.

Lọ́jọ́ Ajé ni Ààrẹ Buhari bu ọwọ́ lu àbá ọ̀hún, lẹ́yìn tó ti kọ́kọ́ ṣèlérí lọjọ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Karùn ún, nínú ọ̀rọ̀ tó bá àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sọ lásìkò àjọ̀dún ètò ìṣèlú àwaarawa láti bu ọwọ́ lù ú.

Ṣùgbọ́n, ojú ti kálùkù ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fi wò ó yàtọ̀ síra wọn. Bí àwọn kan ṣe gbóríyìn fún Ààrẹ Buhari fún ìgbésẹ̀ nà, ni àwọn kan n sọ ìdàkejì lọ́rọ̀.

Aarẹ Buhari bọwọlu òfin
Àkọlé àwòrán, Kíni àbájáde òfin tuntun yìí fún àwọn ọdọ Naijiria?

Adúrà wa ni pé ki òfin yii ru àwọn ọdọ soke lati ṣe rere.

Aarẹ Buhari bọwọlu òfin
Àkọlé àwòrán, Kíni àbájáde òfin tuntun yìí fún àwọn ọdọ Naijiria?

Nínú ọ̀rọ̀ ti rẹ̀, Ààrẹ ilé aṣòfin àgbá, Bukọla Saraki, ní òfin tuntun náà ni ìpìlẹ̀ kíkó àwọn ọ̀dọ́ mọ́ra nínú ètò ìṣèlú, àti pé Nàìjíríà nílò agbára àwọn ọ̀dọ́ fún ìdàgbàsókè rẹ̀.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Kín ni àwọn ará ìlú n sọ?

Ṣe kò sí ti òfin yìí kò fi kan ọjọ orí àwọn sẹnetọ ati gomina? Bẹẹ, kò yẹ ki ìbí ju ìbí lọ

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Àwọn kan gbà pe, o tumọ si pe ki àwọn arúgbó lọ rọ ọ kún sile ni.

Esi lori Teitter

Oríṣun àwòrán, Twitter

Àkọlé àwòrán, Àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà ti n késí ara wọn láti gbégbá ìbò

Kódà, olú ilé iṣẹ́ ilẹ̀ Amẹrika tó wà ní ìlú Abuja nínú ọ̀rọ̀ tí wọn, kí àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà kú oríire fún òfin tuntun náà.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Ẹ̀wẹ́, àwọn kan ní ó yẹ́ kí Buhari bu ọwọ́ lu òfin míì tí ó fi òfin de àwọn tó ti 'dàgbà jù' láti má díje fún ipò ìṣèlú, tí wọ́n sì ti n lo àmì #TooOldToRun láti gbe ìpolongo wọn lẹ́yìn.

Ipolongo #TooOldToRun

Oríṣun àwòrán, Twitter

Àkọlé àwòrán, Àwọn ọ̀dọ́ kan n fẹ́ kí Buhari fi òfin de àwọn tó ti 'dàgbà jù' láti maa dupò ìṣèlú
Amin iyasọtọ kan

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Abimbọla Kazeem: Hábà! Ṣé ìwọ ti sáré pé ọmọ ọdún 40 ni?