INEC: Ẹgbẹ́ òṣèlú méje ni yóò kópa ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

Awon to n dibo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Àtúndì ìbò yó wáyé láti lé dí àlàfò tó ṣí sílẹ̀ nínú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ

Ọjọ́ Abamẹta ni Ìbàràpá yóò yan ẹlòmíì ti wọ́n fẹ́ fi rọ́pò Oloogbe Micheal Adeyẹmọ nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin

Àjọ olómìnira tó n ṣètò ìdìbò ní Nàìjíríà, INEC, ti kéde pé ẹgbẹ́ òṣèlú méje ni yóò kópa nínú àtúndì ìbò tí yóò wáyé ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Ètò ìdìbò náà yóò wáyé láti lé dí àlàfò tó ṣí sílẹ̀ nínú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, látààrí ikú aṣojú ẹkùn náà, tó tún jẹ́ olórí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ọ̀hun, Michael Adeyẹmọ tó papòda lọ́jọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹrin. ọdun 2018.

Michael Adeyemo

Oríṣun àwòrán, facebook/Michael Adeyemo

Àkọlé àwòrán, Abẹnugan ilé aṣòfin ipinlẹ Ọ̀yọ́, Michael Adeyemo jáde láyé lọ́jọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹrin, ọdún 2018.
Àkọlé fídíò, Abimbọla Kazeem: Hábà! Ṣé ìwọ ti sáré pé ọmọ ọdún 40 ni?

Alága àjọ náà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọ̀gbẹ́ni Mutiu Agboke, ló fi ìkéde ọhun síta níbí ìpàdé kan tó wáyé ní ìlú Eruwa l'Ọ́jọ́rú, lori ìmúrasílẹ̀ fún ètò ìdìbò náà.

O ni àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú ọ̀hún ni, Accord, Peoples Democratic Party, All Progressives Congress, tó fi mọ́ Fresh Democratic Party atawọn miran.

Ẹ̀wẹ̀, ó fi kun un pé, ogóje ibùdó ìdìbò ni ètò ìdìbò náà yó ti wáyé jákèjádò ẹ̀kùn ìdìbò Ibarapa. Àti pé, ẹgbẹ̀ta lé mẹ́wàá òṣìṣẹ́ ní yóò tukọ̀ ìdìbò óhun.

Ètò ìdìbò náà ni ìrètí wà pé yó wáyé láàrin agogo mẹ́jọ òwúrọ̀ sí aago méjì ọ̀sán.

Amin iyasọtọ kan

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, 'Isẹ́ Tíátà tí mò ń se ti tó mi jẹun'