Ìjọ Hàkíkà: O leè sùn ti ìyàwó mi, kí ń sùn ti tìrẹ

Hakika

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Asaaju ẹgbẹ Tijjaniyya ti ta kete si ẹgbẹ Hakika yii, ti wọn si ni awọn ko ba wọn se rara.

Bi orilẹ-ede Naijiria se n jẹ ekuru ọran ko tan lori ọrọ ikọ Boko Haram, tun ni ẹgbẹ ẹlẹsin miran tun dide ni awọn ipinlẹ bii Adamawa, Nasarawa ati Kano. Orukọ ẹgbẹ ẹlẹsin naa ni Hakika.

Bi o tilẹ jẹ pe ẹgbẹ yii ni ara ẹka ẹgbẹ ẹlẹsin musulumi Tijjaniyya ni oun wa, amọ awọn asaaju ẹgbẹ Tijjaniyya ti ta kete si ẹgbẹ Hakika yii, ti wọn si ni awọn ko ba wọn se rara.

Eyi ri bẹẹ nitori awọn iwa kan to se ajeji ti awọn ẹlẹsin Hakika maa n hu bii pi paarọ iyawo laarin ara wọn ti wọn ba ti de ipo giga kan ninu ẹsin, kikọ irun kiki silẹ ati kikọ ẹyin si aawẹ gbigba lasiko Ramadan, eyi to jẹ ara opo ẹsin Islam.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Èkó: Àwọn akínkánjú obìnrín tó ń wa Márúwá

Ọkan lara ẹlẹsin Hakika to ba BBC sọrọ labẹ asọ ni oun n foju sọna lati de ipo giga ninu ẹsin naa, nibi ti oun yoo ti ni anfaani lati paarọ iyawo oun pẹlu ẹlomiran..

"Ti mo ba fi lee de ipo giga yii ninu ẹsin, maa gba ẹlomiran ni aaye lati maa sun ti iyawo mi, amọ emi ko ti de ipo naa bayii. Ti o ko ba jẹ ara ikọ ẹlẹsin Hakika, oye imọ yii ko lee ye ọ."

Bakan naa lo ni ti eeyan ba de ipo naa, ti wọn n pe ni ‘Tarbiyatul Askaru’, wọn yoo ya wọn sọtọ lati mase da ẹsẹ, ti wọn si leehu iwa to ba wu wọn lai ro pe ẹsẹ ni wọn n da.

Iha wo ni awọn asaaju ẹsin ati awujọ kọ si Hakika ?

Awọn ọba alaye ati awọn asaaju ẹsin ti wa rọ awọn araalu lati mase dara pọ mọ ijọ Hakika nitori ẹkọ ati ilana wọn yatọ si ti Islam.

Onimọ ẹlẹsin Islam kan ni ilu Numan nipinlẹ Adamawa, Malam Aminu Yakubu, sọ fun BBC pe iwa aimọkan nipa ẹkọ ẹsin Islam lo n da awọn ẹlẹsin Hakika laamu. O fikun pe, igbe aye ‘taa ni yoo mu mi’ ti awọn ẹlẹsin Hakika n hu lo n se iwuri fawọn ọdọ lati tete dara pọ mọ wọn.

Hakika

Oríṣun àwòrán, @ABBAYOLA447

Àkọlé àwòrán, Awọn agbofinro ti wa sọ fun BBC pe awọn ti n finmu-finlẹ nipa ikọ ẹ́lẹsin tuntun naa, tawọn si ti n dọdẹ wọn.

Awọn agbofinro naa n gbe igbesẹ nipa ikọ ẹlẹsin Hakika

Awọn agbofinro ti wa sọ fun BBC pe awọn ti n finmu-finlẹ nipa ikọ ẹ́lẹsin tuntun naa, tawọn si ti n dọdẹ wọn.

Atẹjade kan ti ileesẹ ologun ilẹ wa fisita ni ẹkọ wọn se ajeji, ti awọn si ti n sọ wọn tọwọ-tẹsẹ, ki iwa wọn to bọwọ sori.

Hakika

Oríṣun àwòrán, @ABBAYOLA447

Àkọlé àwòrán, Ọranyan kọ ni gbigba aawẹ Ramadan fun awọn ọmọ ẹgbẹ Hakika

Wọn ni kekere ni awọn ti fẹ pa eekan ikọ ẹlsin Hakika, tori ti wọn ba dagba tan, wọn lee maa gba ẹbọ lọwọ awọn ọmọ ilẹ Naijiria bii Boko Haram. Wọn ni idasilẹ ẹgbẹ Hakika yii gan ti n da ẹru ba awọn eeyan Naijiria, eyi to n ran wọn leti bi ikọ mujẹ-mujẹ Boko Haram se bẹrẹ ni ọdun mẹwa sẹyin.

Kin lo de ti ikọ ẹlẹsin Hakika fi yatọ ?

  • Awọn ọmọ ẹgbẹ Hakika gba pe, ti awọn ba ti de ipo kan to ga ninu iwa mimọ ati ninu ẹsin, awọn lee paarọ awọn iyawo awọn laarin ara awọn
  • Ọmọ ijọ Hakika kii ki irun ni ẹẹmarun ni ojumọ gẹgẹ bi opo ẹsin Islam ti laa kalẹ
  • Ọranyan si kọ ni gbigba aawẹ Ramadan fun awọn ọmọ ẹgbẹ Hakika
  • Wọn ko ni Mọsalasi kankan ti wọn ti n jọsin, tabi ni asaaju kankan ti wọn mọ mọ wọn, to si jẹ peko ko bọ si ojutaye
  • A lee se idamọ awọn ọmọ ijọ Hakika lati ipasẹ ọrọ̀ọ ẹnu wọn, ti wọn fi n tako irun kiki ati aawẹ gbigba
  • Bakan naa ni wọn maa n se iwuri fun iwa pansaga ati agbere
  • Ọpọ wọn lo jẹ ọdọ, ti ọjọ ori wọn si kere pupọ
  • Ikọ ẹlẹsin Hakika kii gbe ibọn tabi lo ohun ija oloro kan-kan